Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pàtó iye ọmọ tó kú níbi àpèjẹ́ Naomi Ogunwusi n'Ibadan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe ọmọde marunlelọgbọn lo ku nibi iṣẹlẹ ikọluraẹni to waye lasiko ti apejẹ opin ọdun ti olori Ooni Ile-Ife nigba kan, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan.

Bakan naa ni ọmọde mẹfa ṣi wa nileewosan nitori wọn farapa kọja aala.

Ọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni iṣẹlẹ naa waye.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Osifeso Adewale fi sita ni ọsan Ọjọbọ, o ni awọn tun ti mu ẹni to ṣonigbọwọ eto naa, Wooli Naomi Silekunola.

Lara awọn ti agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe awọn ti mu ni Fasasi Abdulahi (Ọga agba ile-ẹkọ Islamic High School, Ibadan), Genesis Christopher, Tanimowo Moruf, Anisolaja Olabode, Idowu Ibrahim, ati Abiola Oluwatimilehin.

SP Osifeso sọ pe awọn ti gbe iwadii lori iṣẹlẹ naa le ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n mojuto iwa ọdaran lọwọ fun iwadii to yẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe idajọ to yẹ ni yoo waye lori iṣẹlẹ naa. Bakan naa lo ni ki awọn ara adugbo ti ile-ẹkọ ti iṣẹlẹ ti waye fi ọkan balẹ, paapaa bi wọn o sẹ maa ri awọn ọlọpaa to n lọ, to n bọ ni agbegbe wọn lati dena ki awọn janduku gbakoso.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Oyo kede pe awọn ti mu awọn to ṣeto naa si ahamọ,

Eyi jẹyọ ninu atẹjade ti Gomina Seyi Makinde fi sita.

O ni ijọba yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lori ọr naa.

Ọdọọdun ni Olori Naomi ma n ṣe ariya naa, paapaa niluu Akure to n gbe. Amọ, ilu Ibadan lo ti ṣe eleyi to di wahala bayii.

Iroyin sọ pe eero to pọ ju ninu ọgba ile-ẹkọ Islamic High School, Bashorun, lo mu ki wọn o tẹ ara wọn pa, ti awọn miran si daku nitori ooru to mu wọn.