Wọ́n ti sin òkú Feranmi Akin-Akinye, ọ̀dọ́mọkùnrin tó jábọ́ láti orí Cocoa House

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Wọn ti sin oku Feranmi Akin-Akinye, ọdọkunrin ẹni ọdun mejilelogun to jabọ lati ori ile alaja gogoro Cocoa House to wa niluu Ibadan.

Iroyin ni akẹkọọjade ilẹ ẹkọ Afe Babalola University, to wa niluu Ado Ekiti, (ABUAD) ni oloogbe ọhun, ko to maa kẹkọọ nipa imọ "cybersecurity" ni aja kẹjọ Cocoa House ṣaaju iṣẹlẹ laabi naa.

Ẹnikan to sunmọ oloogbe naa amọ ti ko fẹ fi orukẹ ara rẹ lede sọ pe ọdọ iya rẹ ni Akin-Akinye n gbe lagbagbe Meridian, ni Apata, nigba ti baba rẹ n gbe nilẹ Amẹrika.

Gẹgẹ bi nnkan ti ẹni naa sọ, niṣe ni wọn ni ki Akin-Akinye lọ so akọle nla kan si ori Cocoa House, eyii to jẹ iṣẹ ti awọn akọṣẹmọṣe maa n ṣe pẹlu oniruru irinṣẹ atawọn ohun idaabobo ara ẹni.

O ni "Ileeṣẹ naa ni mo di ẹbi iku oloogbe le lori.

"Ile rere ni ọdọkunrin naa ti wa, o si jẹ oniwa rere, koda, o ni ọkọ ayọkẹlẹ ti awọn obi rẹ ra fun amọ eeyan ko le mọ nitori bo ṣe maa n ṣe bii ọmọluabi.

"Wọn ni ko lọ so akọle nla kan mọ ori ile alaja pupọ naa, eyii to jẹ iṣẹ awọn akọṣemọṣẹ, amọ nitori pe o jẹ ọmọluabi, o gba lati jiṣẹ naa."

Ẹni naa sọ siwaju si pe ileeṣẹ to ṣokunfa iku Akin-Akinye gbiyanju lati ṣe ọrọ naa ni oku oru.

O ni "Wọn sọ pe awọn gbe lọ sile iwosan pajawiri bo tilẹ jẹ pe o ti jade laye, wọn ko tilẹ pe iya rẹ gan, ẹlomiran lo kan si iya rẹ lori aago.

"Nigba ti ileeṣẹ iroyin 32 FM, ti awọn naa ni ọọfisi si Cocoa House fẹ ya fọto rẹ, wọn kọ jalẹ. Wọn sare tete da aṣọ bo oku naa mọlẹ."

Ṣugbọn ṣa, a gbọ pe baba atawọn ibatan oloogbe naa ti n gbe igbesẹ lati pe ileeṣẹ to ti n kẹkọọ cybersecurity naa lẹjọ latari ipa ti wọn ko ninu iku ọdọkunrin ọhun.