Nigeria Huge Debts: Ilé aṣofin fárígá, ó pè fún ìwádìí lórí ìlànà ẹ̀yáwó ìjọba àpapọ̀

Ilé aṣofin fárígá, ó kọ̀ láti fòǹtẹ̀ lu owóyàá tí Buhari fẹ́ gbà lọ́wọ́ CBN

Ile igbimọ aṣofin orilẹede yii ti ṣalaye idi ti ko fi ni buwolu aba aarẹ Muhammadu Buhari lati ya awọn owo kan lati banki apapọ orilẹede yii.

Apapọ owo ti ijọba apapọ ti gba lọwọ banki apapọ ilẹwa bayii lo le ni trilliọnu mejilelogun naira.

Ijọba apapọ ni o ti gba ninu owo naa lọwọ banki apapọ ilẹ yii lai fi iwe ibeere ẹyawo ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin apapọ.

Igbesẹ naa si lo mu oriṣiriṣi awuyewuye lọwọ nitori igbagbọ awọn aṣofin pe igbesẹ naa ku die kato.

Ofin orilẹede Naijiria si lo fun ijọba apapọ ni anfaani lati ya ida marun ninu owo to ba pa wọle.

"Ijọba apapọ ko tọ ọna to tọ lati gba awọn owoya lọdọ banki apapọ ilẹ wa"

Ṣugbọn ijọba apapọ ti bẹrẹ si ni tọwọ bọ owo naa nitori ọda owo to n da a.

Aṣofin Ahmed Babba Kaita, lati ẹkun idibo Daura ni ipinlẹ Katsina, nigba to n da si ijiroro ile lori isẹlẹ yii, ni ọpọlọpọ aiṣedeede ni lo wa ninu ọna ti ijọba apapọ gba na owoyii.

O ni bẹẹ ni ijọba ko si tọ ọna to tọ lati gba awọn owo naa.

Kaita ni asilo agbara aarẹ ni bi wọn ko ṣe gbe iwe ibeere lati ya owo naa wa si ile igbimọ aṣofin.

Sugbọn o ni awọn ko ni buwọlu iwe ibeere fun ẹyawo mii, nitori ki i ṣe gbogbo ohun ti ijọba ba gbe wa si ile igbimọ aṣofin, ni awọn maa buwọlu.

"A ko fẹsun kan ijọba pe ko na owo naa si ọhun to tọ amọ o gbọdọ salaye bo se n na owoya ọhun"

Ahmed Babba Kaita ni awọn ko fẹsun kan aarẹ orilẹede yii pe ko na owo naa daradara ṣugbọn, o gbọdọ ṣalaye ni ọkọọkan nipa ọna to gba na owo naa.

Kaita ni nigbati ẹgbẹ PDP wa ni ijọba, trillionu meji ni ajẹsilẹ ẹyawo naa ṣugbọn lọwọ bayii, ẹyawo ijọba apapọ ti wọ trilliọnu mejilelogun naira.

Ahmed Babba Kaita ni ile igbimo asofin ti gbe igbimọ tẹẹkoto silẹ, ti yoo si fi iwe pe minisita to risi isuna owo, Zainab Ahmed ati Gomina banki apapọ ilẹwa, Godwin Emefiele.

Bakan naa lo ni ile asofin yoo tun ransẹ si awọn osisẹ ọba miran to ohun ṣe pẹlu eto ẹyawo, ti wọn yoo si mu esi aba pada wa siwaju ile igbimọ asofin naa lọdun 2023 to n bo.

Inú mi kìí dùn tí wọ́n bá pè mí ní Jubril Sudan – Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe inu oun kii dun ti awọn eeyan ba n pe oun ni Jubril lati Sudan.

O ni awọn to n pe oun lorukọ naa n ṣe bẹẹ lati mu oju oun kuro lara iṣẹ to yẹ ki oun ṣe fun ilu ni.

Aarẹ Buhari lo sọ ọrọ naa ninu fiimu kan ti wọn ṣe nipa igbesi aye rẹ eyii ti wọn pe ni “Celebrating a Patriot, a Leader, an Elder Statesman.”

Inu fiimu ọhun lo ti sọrọ naa atawọn ọrọ mii ninu ifọwerọ rẹ.

Ta ni Jubril lati Sudan?

Ọdun 2018 ni ọrọ ikede ‘Jubril lati Sudan’ naa kọkọ ṣẹyọ nigba ti Buhari pada de si Naijiria lati ilẹ Gẹẹsi lẹyin to lọ lo ọpọ ọjọ lati tọju aisan kan to n ba finra.

Bo ṣe de bayii lawọn kan n sọ pe Aarẹ ti ku, ati pe ọkunrin kan to n jẹ Jubril, ọmọ orilẹ-de Sudan ni wọn gbe pada wa si Naijiria, to si n ṣe bii Aarẹ.

Nigba to n sọrọ lori ọrọ ọhun, Buhari ni ọrọ naa ko pa oun lẹrin rara, amọ awọn ti wọn ko fẹ ki oun gbajumọ iṣẹ ti wọn dibo yan oun fun, lo n gbe iroyin ẹlẹjẹ bẹẹ kiri.

O ni “Ohun to ka mi lara ni bi mo ṣe maa ṣe awọn ohun amayedẹrun fun awọn araalu.”

"Aisan ‘Sickle Cell’ ṣekupa meji ninu awọn ọmọ mi ni mo ṣe fẹ́ Aisha"

Aarẹ Buhari tun ti sọ pe meji lara awọn ọmọ oun lo ba aisan ‘Sickle Cell’ lọ.

Buhari lo fi ọrọ naa lede lọjọ Ẹti, nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrin ọdun rẹ, eyii ti awọn ẹbi atawọn ọrẹ rẹ gbe kalẹ fun.

Nigba to n sọrọ nipa iriri aye rẹ, o ni awọn ọmọ oun meji ti iyawo oun akọkọ ti orukọ rẹ n jẹ Safinatu bi fun oun ku nitori aisan naa.

O ni ẹyin ti oun pade Aisha Buhari ni oun lọ ṣe ayẹwo ẹjẹ, ki irufẹ nnkan bẹẹ ma ba waye mọ.

Ọdun 1971 ni Buhari fẹ Safinatu, wọn si bi ọmọ marun un fun ara wọn.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ohun tí Ààrẹ Buhari sọ fún àwọn Kristẹni rèé lásìkò ayẹyẹ ọdún Keresimesi

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ki awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria ku ayẹyẹ ọdun Keresimesi.

Buhari lo fi ikinni naa sita ninu atẹjade kan, nibi to ti sọ pe ọdun Kersimesi ti ọdun 2022 yii ni yoo jẹ aṣemọ ohun gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria.

O ni bo tilẹ jẹ akoko jẹ eyii ti awọn eeyan fi maa n yọ mọ ara wọn, ti wọn a si maa fun ara wọn ni ẹbun, o tun jẹ akoko to yẹ ki awọn araalu wa ni iṣọkan, lai wo ti ẹya, ede, tabi ẹsin.

Buhari sọ pe “Keresimesi ọdun yii ni yoo jẹ ikẹyin iru rẹ fun mi gẹgẹ bii Aarẹ yin ti ẹ dibo yan.”

“Lati ọdun meje sẹyin ni mo ti lanfaani lati maa gbalejo awọn ọmọlẹyin Kristi lasiko ọdun Keresimesi yato si asiko ajakalẹ arun Corona, mi o ni gbagbe ifẹ ti awọn eeyan n fi han si mi ni gbogbo asiko naa.”

“O ṣe pataki fun mi lati maa ranti pe ko si ọna miran lati ṣajọyọ ọdun Keresimesi ju ki a fi ifẹ ati aanu han si ọmọlakeji wa lọ.”

Buhari wa gba awọm ọmọ Naijiria niyanju lati na ọwọ si awọn alaini lasiko ọdun naa.

O tun sọ pe asiko ọdun naa jẹ asiko lati pinnu lati fọwọsowọpọ fun itẹsiwaju orilẹ-ede Naijiria.

Aarẹ sọ pe oun yoo tẹsiwaju lati pese abo to peye fun awọn araalu titi ti oun yoo fi kuro lori alefa.

O pari ọrọ rẹ pe gbogbo awọn to n gbiyanju lati da omi alaafia Naijria ru ko ni ṣaṣeyọri.