Ìjọba dá ìrìnàjò ọkọ̀ ojú'rin láti Abuja sí Kaduna dúró lẹ́yìn ìjàmbá tó ṣẹlẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ to n mojuto eto irinna ọkọ ojurin ni Naijiria, NRC, ti da irinajo ọkọ reluwee lati Abuja si Kaduna duro.

Kayode Opeifa to jẹ ọga agba ajọ NRC lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin niluu Abuja lẹyin ijamba ọkọ oju irin to ṣẹlẹ lanaa Iọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii ni nnkan aago mọkanla.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ọrọ di boo lọ, yago fun mi fun awọn ero inu ọkọ reluwee naa nigba to yi danu tan.

Ọga agba ajọ NRC ti sọ pe awọn akọṣẹmọṣẹ nipa eto abo ti lọ sibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ lati tọpinpin nnkan to ṣokunfa rẹ.

Opeifa tun fidi rẹ mulẹ pe irọ to jinna soootọ ni iroyin kan tawọn eeyan kan n gbe kiri pe ọkọ oju irin to danu naa ko dangajia to.

Eeyan meje lo farapa ninu ijamba ọkọ oju irin to ṣẹlẹ

"Gbogbo eeyan to wa ninu ọkọ oju irin to ṣubu jẹ 618, eeyan 583 ninu wọn lo jẹ ero nigba ti mẹẹdogun jẹ oṣiṣẹ àjọ NRC.

Oṣiṣẹ eleto ilera kan, awọn to n se ounjẹ mọkanla ati awọn agbalẹ mẹjọ.

Gbogbo àwọn eeyan yii pata ni a rí ko kuro ninu ọkọ oju irin to danu naa.

Eeyan meje lo farapa ninu gbogbo awon to wa ninu ọkọ naa, lẹsẹ k'ẹsẹ naa si ni a ti fi ambulansi gbe wọn lọ sile iwosan fun ìtọjú.

A si ko gbogbo ero to kù pada si ibudokọ reluwee to wa ni Kubwa ati Idu, onikaluku wọn sì ti padà sí ilé wọn," Opeifa lo sọ bẹẹ ninu atẹjade ti àjọ NRC fi sita.

Ọga agba àjọ NRC fikun ọrọ rẹ pe ajọ naa ti da owo awọn ero tọrọ kan pada.

Ṣaaju ni Aarẹ Bola Tinubu to wa nibi ipade kan lorilẹede Brazil ti sọ pe ijamba ọkọ oju irin naa ba oun lọkan jẹ.

Tinubu ni oun n reti ẹkunrẹrẹ nnkan to ṣẹlẹ gan an ki awọn tọrọ kan le ri pe wọn daabo bawọn ero inu ọkọ oju irin naa.

Tinubu ni ajọ NRC ti ṣe ojuṣe wọn lori ijamba naa, ati pe wọn tun ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lati dena iru iṣẹlẹ bayii lọjọ iwaju.

Aarẹ ni oun gbadura ilera to peye fawọn ero inu ọkọ oju irin naa ti wọn farapa nibi ijamba to ṣẹlẹ.

Bi ijamba ọkọ oju irin naa ti ṣẹlẹ

Ajọ NRC fidi rẹ mulẹ pe ọkọ oju irin ọhun tawọn ero wa ninu rẹ danu loju ọna rẹ lati Abuja lọ si Kaduna laarọ ọjọ Iṣẹgun.

Ọkọ oju irin ọhun ko tii rin ju kilomita mọkandinlaadọta laarin ibudokọ reluwee to wa ni Kubwa ati Asham lọ nigba to ṣadeedee kuro loju irin rẹ to si yi danu.

Ajọ NRC sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe lẹsẹ kẹsẹ lawọn oṣiṣẹ eleto ilera atawọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri ti lọ sibi ti ijamba naa ti waye lati ṣe iranwọ fawọn to wa ninu ọkọ to danu ọhun.

Ọga agba ajọ NRC ṣalaye pe awọn ẹṣọ eleto abo naa wa nibẹ lati ri pe eto idoola awọn ero ọkọ oju irin naa lọ ni irọwọ rọsẹ.

Fidio kan to lu ori ayelujara pa ṣafihan bawọn ero to jade ninu ọkọ to danu naa ṣe duro kaakiri ibi ti ijamba ọhun ti ṣẹlẹ.

Fidio naa tun ṣafihan bi awọn ara ọkọ oju irin naa ti doju de.

Ajọ to n moju to irinajo ajọ ọkọ oju irin ko tii sọ pato nnkan to ṣokunfa ijamba ọhun.

Kii saba sewu ninu irinajo ọkọ oju irin ni Naijiria, yatọ si iṣẹlẹ ijinigbe to ṣẹlẹ lọdun 2022 nigba tawọn janduku agbebọn ṣe ikọlu si ọkọ oju irin to n lọ si Kaduna lati Abuja nibi ti wọn ti ji awọn ero inu ọkọ reluwee naa lọ.

Iṣẹlẹ mii tun waye lọdun 2023 nigba tawọn agbebọn tun ji awọn ero ọkọ oju irin gbe lọ nipinlẹ Edo.

Ko din ni eeyan mẹẹdogun to ku nibi iṣẹlẹ naa, nigba eeyan to le aadọjọ si di awati.