You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kókó ìpàdé bònkẹ́lẹ́ Atiku, El Rufai àtàwọn adarí ẹgbẹ́ ADC míì l'Abuja ṣáájú ìbò ààrẹ 2027
Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar, gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Nasir El-Rufai, David Mark atawọn adari ẹgbẹ oṣelu ADC mii ṣe ipade bonkẹlẹ niluu Abuja lanaa Ọjọbọ, ṣaaju eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.
Iroyin sọ pe ko si ẹni to mọ ibi ti ipade naa ti waye niluu Abuja l'Ọjọbọ.
Lara awọn to wa nibi ipade ọhun ni gomina ipinlẹ Sokoto tẹlẹ ri, Aminu Tambuwal ati gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ, Abdulfatai Ahmed.
Awọn abẹnugan lagbo oṣelu mii to wa nibi ipade naa ni minisita igbokegbodo ọkọ tẹlẹ, Rotimi Amaechi ati minisita fun ọrọ aje ori ayelujara tẹlẹ, Isa Pantami.
Loju opo X rẹ ni Atiku ti sọ fawọn eeyan wi pe oun ti wa nibi ipade naa, o ni eyi ṣapejuwe ikorajọpọ alatako to fẹsẹ mulẹ.
Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ sọ pe ipade ẹgbẹ oṣelu ADC jẹ ipade kan to tako awọn alagbara ati olowo to n ṣagbatẹru oṣi ati eto abo to mẹhẹ.
Atiku ni ADC ṣetan lati rọpo Aarẹ Bola Tinubu pẹlu olori ti yoo dari orilẹede Naijiria daadaa.
Koko ipade awọn adari ẹgbẹ oṣelu ADC l'Abuja
Ipade to waye niluu Abuja da lori wiwa ni iṣọkan gẹgẹ bii ẹgbẹ alatako lati le koju ẹgbẹ oṣelu APC ijọba to wa lode ninu eto idibo ọdun 2027.
Alaga ẹgbẹ ADC to jẹ aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja tẹlẹ, Mark, lo dari ipade ọhun.
Wọnyi ni koko to jẹyọ nibi ipade awọn abẹnugan ADC niluu Abuja gẹgẹ bi akọwe iroyin ẹgbẹ naa, Bolaji Abdullahi ṣe sọ:
Gbogbo awọn to fẹ dupo aarẹ fẹnu ko pe awọn yoo ṣatilẹyin fun ẹnikẹni to ba wọle ibo abẹnu fun oludije sipo aarẹ fun eto idibo ọdun 2027.
Nnkan keji ti wọn fẹnu ko le lori nibi ipade naa ni pe kawọn ọmọ ẹgbẹ to ba si wa ninu ẹgbẹ oṣelu mii kọwe kuro nibẹ ki wọn si kọju mọ ADC nikan.
Koko kẹta ti wọn fẹnu ko le lori nibi ipade ọhun ni pe igbimọ amuṣẹya yoo kede igba ti eto idibo abẹnu yoo waye ṣaaju ibo gomina to n bọ nipinlẹ Osun ati Ekiti.
Ọdun 2005 ni wọn kọkọ da ẹgbẹ oṣelu ADC silẹ, amọ, orukọ ti wọn n pe e nigba naa ni Alliance for Democratic Change.
Lọdun 2011 ni wọn forukọ ẹgbẹ naa forukọ silẹ pẹlu ajọ eleto idibo Naijiria, INEC.
Loṣu Keje to kọja ni agbarijọpọ awọn oloṣelu ti wọn koro oju si iṣejọba ẹgbẹ APC to wa lode kora jọ pọ lati inu oniruuru ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria ti wọn si darapọ mọ ADC.
Lara awọn abẹnugan to ti darapọ mọ ADC ni gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ, Rauf Aregbesola, alaga ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ, John Odigie-Oyegun, Dino Melaye, Uche Secondus ati Emeka Ihedioha.
Ọpọ eeyan lo ti n sọ pe o ṣee ṣe ki Atiku, Peter Obi, ati Amaechi wa lara awọn ti yoo kopa ninu eto ibo abẹnu ADC fun oludije sipo fun ibo aarẹ ọdun 2027.