Ayédèrú ṣuga ti wà lọ́jà, ẹ fura – Ìjọba àpapọ̀ kìlọ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n risi idabobo ohun jijẹ ni Naijiria, FCCPC, ti pe akiyesi awọn araalu si ṣuga kan to wa lọja, eyi ti wọn pe ni ayederu ti awọn kan ko wọle lati orilẹede Brazil.

FCCPC lo ikilọ naa sita ninu atẹjade kan to fi soju opo Twitter ati Facebook rẹ.

Orukọ awọn ṣug naa ni; Grupo Moreno, Terous, USI S. Joao, Alvean ati Arapora Bionergia eyii ti wọn ni ko ni eroja Vitami A ninu, to si le ṣe akoba nla fun ilera awọn araalu.

Ijagwu ni iwadii ajọ naa fihan pe awọn ṣuga yii ni wọn ko ni orukọ lara, bẹẹ ni wọn ko ni ọjọ ti wọn sẹda rẹ lara ati ọjọ ti yoo bajẹ.

Bakan naa ni ajọ ọhun sọ pe awọn ṣuga naa ko ni nọmba idanmọ ajọ NAFDAC lara.

Gẹgẹ boo ohun to wa ninu atẹjade ọhun, awọn ṣuga naa pọ biba ni ilẹ Yoruba ati ni apa ariwa orilẹede Naijiria.

FCCPC ni “Ohun to n kọ wa lominu ju ni pe awọn ṣuga yii ni wọn ko ni eroja vitami A ninu, eyi to ṣe koko fun ki oju ma riran ati alaafia gbogbo ara.

“Aisi eroja yii le ṣe akoba nla, o le fa ifọju ati ọpọlọpọ aarun paapa fun awọn ọmọde ati alaboyun."

Bakan naa ni FCCPC ni awọn tun kominu lori ipa ti awọn ayederu ọja yoo ni ninu ọja.

“A n fi da gbogbo araalu loju pe, pẹlu ilana ti ofin gbe kalẹ, a ti n gbe igbesẹ lati wa ojutu si iṣoro yii. Ajọ yii ti n kọ awọn aaralu nipa ewu to wa ninu jijẹ awọn ounjẹ bi ṣuga ti a ko buwọlu fun jijẹ.

“A n rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ṣe iwadii daada lati mọ boya awọn ounjẹ wọnyi yii ni nọmba idanimọ NAFDAC ki wọn to jẹ.”

FCCPC ni iṣẹ ti bẹrẹ pẹlu ajọ NAFDAC, ileeṣẹ asọbode ati awọn ajọ alaabo mii ni Naijiria lati ko awọn ayederu ṣuga naa kuro nilẹ.