Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Ko see ma gboo
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Ọmọ dàpọ̀ ní wọ́ọ̀dù,ẹgbẹ oṣelu meji forukọ kan naa ranṣẹ si INEC fun idibo ọdun 2027.

Ẹgbẹ oṣelu 'All Democratic Alliance' (ADA) ati Advanced Democratic Alliance ni wọn jọ mu orukọ kan naa.

Alaga INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, fidi eyi mulẹ.

O ṣalaye ilana ti yoo yanju rẹ labẹ ofin

Ati ohun ti ẹgbẹ gbọdọ ni ko too forukọ silẹ

Alaye wa loju opo wa.

…………………………………………………………………….

Owó epo rọ̀bì já wálẹ̀ lẹ́yìn tí Israel àti Iran gbà láti dáwọ́ ogun dúró.

Ọpẹ o.

Iroyin sọ pe epo Brent Crude ti wọn fi n ṣe odiwọn owo epo lagbaaye, dinku ni ida marun lẹyin ti wọn gba lati sinmi ogun.

Ṣe o wa kan Naijiria bi?

Lọ si BBC.COM/Yoruba lati mọ ipa ti ogun naa n ni lara owo epo Naijiria

MMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMM

Ile ẹkọ Polytechnic Ibadan pa orukọ da, o di Victor Omololu Olunloyo Polytechnic.

Oni Ọjọbọ ni Gomina Seyi Makinde, kede ayipada naa nibi isinku Oloogbe Olunloyo n'Ibadan.

Oloogbe Olunloyo to ti jẹ gomina Oyo ri, ni ọga agba akọkọ fun ile ẹkọ Gbogboniṣe ilu Ibadan.

Fun ẹkunrẹrẹ.