You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ohun tí ọlọ́pàá sọ nípa àwọn tó n pe ara wọn ní ‘Jagaban Army’
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe oun yoo ṣe iwadii nipa awọn eeyan kan ti wọn n pe ara wọn ni ‘Jagaban Army’ lati mọ irufẹ ẹni ti wọn jẹ ati boya wọn le ṣakoba fun abo araalu.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Olumuyiwa Adejobi lo sọ bẹẹ loju opo Twitter rẹ.
Ọrọ naa jade lasiko to n fesi si ọrọ awọn eeyan kan pe ẹgbẹ oṣelu kan le lo awọn eeya ọhun fun iwa janduku ati idaluru lasiko eto idibo to n bọ.
Adejobi ni “Emi ko tii gbọ nnkankan nipa awọn eeyan wọnyii o, amọ mo maa ṣe iwadii.”
“O jẹ ajoji si mi gẹgẹ bii ẹnikan, mo si gbagbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko mọ nnkankan nipa wọn.”
Lẹyin naa lo rọ awọn araalu lati fi iwe ranṣẹ si ileeṣẹ naa loju opo [email protected] ti wọn ba ni ohunkohun lati sọ lori awọn eeyan ọhun.
Awọn wo ni Jagaban Army?
Iroyin ni awọn kan lo ko ara wọn jọ lati ṣe ipolongo ibo fun oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn eeyan naa ṣeleri lati ṣiṣẹ fun Tinubu ko le wọle gẹgẹ bii Aarẹ naijiria lẹyin eto idibo naa pẹlu gbogbo agbara wọn.
Wayi o, ọpọ awọn araalu lo ti n bu ẹnu atẹ lu igbeṣe awọn eeyan naa, paapaa latari bi wọn ṣe da aṣọ to farajọ ti ologun fun ara wọn lai gba aṣẹ lọwọ ijọba.
Gẹgẹ bii ohun ti awọn eeyan naa n sọ, bii ere, bii awada ni awọn ọmọ ẹgbẹgun agbesumọmi maa n bẹrẹ, ijọba si gbọdọ ti ọwọ awọn eeyan to n pe ara wọn ni ‘Jagaban Army’ naa bọ aṣọ.