Ọkọ̀ ojú omi tó kó èèyàn 300 dojúdé ní Central African Republic, èèyàn 58 jáde láyé

Ko din ni eeyan mejidinlọgọta to ti dagbare faye ni Central African Republic bayii lẹyin ti ọkọ oju omi gbe wọn danu.

Awọn alaṣẹ sọ pe ero to pọ ju ninu ọkọ naa lo jẹ ko dojude.

Iroyin ni nnkan bi ọọdunrun (300) eeyan lo wa ninu ọkọ oju omi naa to n lọ sibi eto isinku kan ko to danu.

Ori omi Mpoko, lẹba ilu Bangui, to jẹ olu ilu orilẹede naa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Fidio kan to ṣafihan ijamba ori omi naa lori ayelujra ṣafihan bi awọn eeyan ṣe n jabọ sinu omi ti wọn si n gbiyanju lati luwẹ lọ seti odo ọhun.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ọkọ oju omi yoo danu ni CAR.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun ileeṣẹ iroyin RFI pe “iṣẹlẹ yii jẹ eyii to ba eeyan lẹru gidi.

“Mo mọ ẹbi kan to padanu eeyan meje ninu iṣelẹ laabi yii.”

Nigba to n sọrọ lori redio Radio Guira, ọga agba ileeṣẹ to n ri si ọrọ abo araalu, Thomas Djimasse sọ pe awọn adoola ẹmi ti ri oku eeyan mejidinlọgọta yọ ninu omi.

O fi kun pe awọn ko le sọ ni pato iye eeyan to ṣi wa labẹ omi ọhun.

Wa yi o, iroyin ti fidi rẹ mulẹ pe ọpọ awọn to wa ninu ọkọ oju omi naa lo ti n gba itọju lawọn ile iwosan to wa niluu Bangui.