Portable Zazzuu wọ gàù lọ́dọ̀ ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá torí ọ̀rọ̀ ẹ̀nú rẹ̀

Olorin Takasufe, Habeeb Okikiola ti ọpọ mọ si Portable Zazu lo ti wọ gau lọwọ ọlọpaa lorilẹede Naijiria.

Eyi ko ṣẹyin bi o ṣe sọ ninu fidio kan pe oun loun da ẹgbẹ okunkun ‘One million boys’ ati ‘Ajah Boys’ silẹ.

Eyi lo mu ki ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria fi lede pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori olorin naa ati ọrọ to sọ pe oun lo n da ẹgbẹ okunkun ‘one million boys’ silẹ.

Emi ni mo da ‘One million boys’ , ‘Ajah Boys’ silẹ

Ninu fidio ti ko ju iṣẹju aya mẹjọ lo ni olorin takasufe ‘Portable’ naa ti kede pe oun lo da ẹgbẹ okunkun ‘one million boys’ silẹ ati ‘Ajah boys’.

Ninu fidio naa to ṣe lo ti sọ pe ‘ẹ gbọ mi daadaa, njẹ ẹ ti gbọ nipa awọn Ajah Boys, One million Boys, emi ni mo da wọn silẹ.’’

Bakan naa lo darukọ eniyan kan to jẹ ẹlẹri oun pe oun loun ẹgbẹ okunkun naa silẹ.

O ni ‘’Ẹ lọ beere lọwọ Sammy Larry.’’

Kete to sọ ọrọ naa tan ni awọn eniyan ti bẹrẹ si ni fesi si fidio naa lori ẹrọ ayelujara.

Ẹgbẹ okunkun mejeeji naa si ti ṣọṣẹ nipinlẹ Eko ati awọn agbegbe kan nipinlẹ Ogun.

Ọjọ si ti pẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa ti n wa awọn to n ṣagbatẹru ikọ ẹgbẹ okunkun yii.

Eyi lo mu ki ileeṣẹ ọlọpaa paṣẹ ki wọn ṣewadii olorin naa lori ọrọ to sọ.

Ẹ ṣewadii Portable Zazu lori idasilẹ ẹgbẹ okunkun ‘One Million Boys’ – Ọga Agba Ọlọpaa

Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Alkali Baba ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii lori ọrọ ti olorin Takasufe, Portable sọ pe oun lo wa ni idi awọn ẹlẹgbẹ okunkun ni ipinlẹ Eko ti wọn n pe ni ‘One million boys.’

Eyi ko ṣẹyin fidio ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Muyiwa Adejobi fi sita pe iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ rẹ.

‘’Ati bẹrẹ iwadii fidio kan ti olorin Habeeb Okikiola ti ni oun lo da ‘One million boys’ silẹ.’’

‘’Ọga Agba Ọlọpaa ti paṣẹ fun kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko lati bẹrẹ iwadii ni kiakia, ki wọn si se ohun to to labẹ ofin lati ṣe iwadii finifini lori ọrọ naa.

Bakan naa ni wọn fikun un pe awọn n gbe igbesẹ naa lati ri pe opin de ba iwa ọdaran lorilẹede Naijiria.

Awọn ‘’Fans’’ mi ni ‘One million boys’ kii ṣe ẹgbẹ okunkun

Olorin tafasufe naa ninu fidio tuntun to ṣe ti ni ‘one million boys’ ti oun sọrọ nipa rẹ ni awọn ololufẹ oun.

O ni oun kii ṣe ole ati pe ọmọ jẹjẹ ni oun, ki ẹnikẹni ma pa irọ mọ oun, ki wọn si ma ba ogo oun jẹ.

‘’Bi Pasitọ se ni ero miliọnu kan lẹyin, ti Babalawo ati Alfa ni ero miliọnu kan lẹyin, ni emi naa ni ero one million boys lẹyin.’’

‘’Emi o ki n ṣe ole o, awọn ololufẹ mi ni awọn ‘one million boys’ ti mo sọ, kii ṣe awọn to n ja ole kiri.’’

‘Angeli ni mi, tẹ ba ṣe ika fun mi, mi o kii se ole, anibọn ma jale ni mi’’

Bakan naa lo fikun un pe ki ẹnikẹni ma ba ogo ati irawọ oun jẹ.