Ọlọ́pàá Kwara bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ikú Mojisola Awesu tó jáde láyé lẹ́yìn tó bá ọkùnrin lọ ilé ìtura

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ iwadii lori iku akẹkọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Mojisola Awesu, ti wọn ba oku rẹ lori akitan.

Akẹkọọ ile ẹkọ iṣẹgun Kwara State College of Health Technology, ni Mojisola ki wọn to ri oku rẹ.

Iroyin ni Mojisola di awati lẹyin ti ọrẹ rẹ kan bẹẹ lọwẹ pe ko tẹle ọrẹ oun mii to jẹ ọkunrin lọ ode ariya, ko si ṣe bii ọrẹbinrin ọkunrin naa ko le gba owo ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun marundinlogun naira.

Agbẹnusọ ileeṣe ọlọpaa Kwara, DSP Toun Ejire-Adeyemi, ti fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade kan.

Bawo ni Mojisola ṣe di awati?

Ọlọpaa sọ ninu atẹjade naa pe ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii ni wọn fi to ileeṣẹ naa leti pe oloogbe ọhun di ẹni ti wọn n wa.

O ni “Lọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024, ni nnkan bii aago mẹrin abọ irọlẹ, omidan kan, Blesson O, to n gbe lagbegbe Gbomi, niluu Offa, nipinlẹ Kwara sọ fun wa pe alabagbe oun ninu yara kan naa, Omidan Mojisola Awesu, ẹni ọdun mọkanlelogun to jẹ akẹkọọ Kwara State College of Health Technology, ti di awati lati ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹjọ.

“Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, Mojisola gba ipe lati ọdọ Omidan kan ti orukọ rẹ n jẹTimileyin, to ni ko yọju sibi ode ariya kan ti yoo waye ni fasiti Summit ati Al-HikmaH, niluu Ilorin.

“Omidan Timileyin fa Mojisola le Ọgbẹni kan to n jẹ Adebayo Happiness lọwọ, to jẹ akẹkọọ fasiti Summit, ti Adebayo si ni ko ba oun lọ ode ariya nibi ti yoo ti dibọn gẹgẹ bii ọrẹbinrin oun ti oun yo si fun ni ẹgbẹrun marundinlogun naira.”

Ọlọpaa ṣalaye pe nigba ti oloogbe ọhun yoo de ibẹ, o pe alabagbe rẹ pe ile itura ti Adebayo Happiness fi oun si ko tẹ oun lọrun ati pe ko si ayẹyẹ kankan to n waye nibẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, lẹyin to fi ọrọ naa ranṣe si alabage rẹ tan ni ẹrọ ilewọ rẹ ku ti ko si si aaye lati kan si mọ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye siwaju si pe awọn ti tare ọrọ naa lọ si ẹka CID fun iwadii ni kikun.

Kọmiṣọna ọlọpaa, CP Victor Olaiya si ti ṣeleri lati tu iṣu de isalẹ ikoko iṣẹlẹ naa.