Wo bí àwọn èèyàn ìlú Sagamu ṣe ń fojú sọ́nà fún ìjà Anthony Joshua àti Francis Ngannou lọ́la

Bi ija laarin Anthony Joshua ati Francis Ngannou ṣe ku ọjọ kan pere niluu Riyadh ni Saudi Arabia, awọn eeyan ilu Sagamu ni ipinlẹ Ogun to jẹ ilu baba Joshua n foju sọna fun ija naa.

Ọkan lara ẹbi Joshua to n gbe ni ilu Sagamu, Raymond Ajakaye sọ pe "ajogunba ni ẹṣẹ kikan jẹ fun Joshua nitori inu ẹjẹ lo ti ba a.

Eeyan lile ni gbogbo wa ninu ẹbi wa, lati ori baba-baba mi to fi dori baba Joshua gan an.

A maa n ja gan-an, ibi ni mo ro pe Joshua ti ri ẹbun ẹṣẹ kikan."

Awọn eeyan bii idaji miliọnu lo n gbe ni ilu Sagamu gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ eleyii tawon ọdọ pọ ninu wọn.

Ọpọ awọn ọdọ to wa ni ilu yii lo ri Joshua gẹgẹ bi awokọṣe rere.

Koda, awọn kan da ẹgbẹ ololufẹ Anthony Joshua Fan Club silẹ ni ilu Sagamu, bakan naa ni wọn fi orukọ rẹ sọ opopona kan niluu naa.

Orukọ opopona ọhun n jẹ "Cinema Road" tẹlẹ ki ijọba to yipada si orukọ Anthony Joshua lẹyin to pegede lagbo ẹṣẹ kikan.

Koda, ni opopona yii l'awọn ololufẹ Joshua ti maa n ṣe ipade.

Anthony Joshua ni ifẹ Naijiria lọkan

Bo tilẹ jẹ pe orilẹ ede UK ni wọn bi Anthony Joshua si lọdun 1989, ti baba rẹ jẹ ọmọbibi Naijiria, o maa n ṣe afẹri orilẹ ede Naijiria nigba gbogbo.

Lootọ ni pe orilẹ ede UK ni Joshua n ṣoju ninu idije ẹṣẹ kikan, amọ, o kawe ni Naijiria nigba ewe rẹ eyi to jẹ ki o mọ nipa ilẹ Africa daadaa.

Joshua ya tatuu ilẹ Africa si ejika rẹ eleyii to tun n ṣe afihan aala orilẹ ede Naijiria.

Bakan naa, Joshua ti lo orin awọn olorin Naijiria bii Burna Boy ati Femi Kuti lati wọle si gbagede ija lọpọ igba.

Nigba kugba ti Joshua ba n ja, niwaju aafin Ọba Akarigbo ilu Sagamu ni ọpọ eeyan ilu naa ti maa n wo ija rẹ lori tẹlifisan nla.

Ajakaye ni "Joshua jẹ onírẹlẹ eeyan to n bọwọ fun agba."

Kayode Segun-Okeowo to jẹ aarẹ ẹgbẹ ololufẹ Anthony Joshua Fans Club sọ pe o ti di aṣa fawọn araalu Sagamu lati maa ṣe atilẹyin fun Joshua nigba kugba ti o ba ti n ja.

"Ọdun 2016 ni a da ẹgbẹ naa silẹ, awọn ọmọ ẹgbẹ naa si pọ daadaa.

Mo gbagbọ pe Joshua yoo borí ninu ija rẹ ọjọ Ẹti.

Mi o ri Ngannou gẹgẹ bi ẹni to le bori Joshua," Segun-Okeowo lo sọ bẹẹ.

Ija laarin Joshua ati Ngannou yoo ran ọpọ leti orogun to wa laarin Naijiria ati Cameroon lagbo ere idaraya.

Amọ, fun awọn eeyan ilu Sagamu, Joshua nikan ni wọn ri gẹgẹ bi ẹni ti yoo bori lọla.