You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ ọmọ ‘Yahoo’ tó lu ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ pa nítorí owó ‘maga’
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi ṣikun ofin mu afurasi ọmọ Yahoo ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan lori ẹsun pe o lu ọrẹbinrin rẹ pa lagbegbe Eredu Ishara.
Ọlọpaa ni akẹkọọ ipele HND 1 nile ẹkọ gbogboniṣe Gateway Polytechnic ni oloogbe ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Idowu Buhari, ki afurasi naa to gba ẹmi lẹnu rẹ.
Alukoro ileeṣọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, SP Abimbola Oyeyemi sọ ninu atẹjade kan pe ṣe ni afurasi naa ti oloogbe ọhun ati ara rẹ mọ inu raya kan to si bẹrẹ si n lu nilu bara, nibi to ti fọ ori rẹ mọ ogiri.
Awọn ti ọrọ naa sọju wọn sọ pe awọn alabagbe afurasi naa gbiyanju lati ja ilẹkun yara rẹ lasiko ti o n oloogbe ọhun amọ pabo ni gbogbo igbiyanju wọn ja si.
Inu agbara ẹjẹ ni a ti ba Idowu
Oyeyemi sọ pe nigba ti awọn ọlọpaa de ile naa, pẹlu agidi ni wọn fi ja ilẹkun yara ti Idowu ku si ninu agbara ẹjẹ.
O ni wọn gbe digbadigba lọ sile iwosan amọ o ti dakẹ ki wọn to de ile iwosan naa.
“Iṣe Yahoo ni afurasi naa n ṣe”
Awọn akọroyin to ṣabẹwo sile ti iṣẹlẹ naa ti waye jabọ pe akẹkọọ Gateway Polytechnic ni oloogbe naa amọ afurasi kii ṣe akẹkọọ ile ẹkọ naa.
Nigba ti wọn de ile ti iṣẹlẹ naa ti waye, ọlọdẹ ile ọhun ṣalaye pe ija kekere kan lo waye laarin awọn ololufẹ mejeji ki afursi to lu ọrẹbinrin rẹ ọhun pa.
O ni lasiko ija naa ni ẹrọ ilewọ oloogbe ọhun fọ, bakan naa ni wọn ba ẹrọ amohunmaworan inu yara ọhun jẹ pẹlu.
Awọn eeyan adugbo naa ṣalaye pe ọmọ Yahoo ni afurasi naa bo tilẹ jẹ pe o maa n sọ pe iṣẹ gbẹgilere ni oun n ṣe.
Ọwọ oloogbe ni owo yahoo mi wa, o si kọ lati fun mi – afurasi
Nigba ti awọn akọroyin yoo fi de olu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abeokuta lati ba afurasi naa sọrọ ni Eleweran, o ni kii ṣe pe oun lo oloogbe naa fun oogun owo.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, inu apo banki oloogbe ni awọn ‘maga’ ti oun n lu ni jibiti maa n fi owo ranṣẹ si.
Ohun to si fa ija laarin wọn ko ju pe oun bere awọn owo naa lọwọ rẹ, ṣugbọn o kọ lati fun oun, to si sọ pe ‘idi ti jẹ.’
Bo tilẹ jẹ pe afurasin ọhun ni oun fẹran oloogbe naa de ọkan ti oun ko si ro ibi si ṣaaju iṣẹlẹ naa, oun ti ṣetan lati gba idajọ eyikeyi ti ijọba ba da fun oun.