You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ipa ti iléeṣẹ́ ìfọpo Warri àti Port Harcourt tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà yóò ní nínú ìgbé ayé rẹ
Awọn onimọ nipa eto ọrọ aje ti kan saara si igbiyanju orilẹede Naijiria lati se atunṣe si ileeṣẹ ifọpo meji laarin ọdun kan.
Ọjọgbọn Kabiru Isa Dandago, to jẹ onimọ nipa ọrọ aje ni fasiti Bayero niluu Kano ni, iṣẹ ti ijọba apapọ ṣe ni ileeṣẹ ifọpo Warri yoo se ọpọ iranwọ fun eto ọrọ aje Naijiria ni ọpọlọpọ ọna.
"Ni bayii ti Naijiria ti ni ileeṣẹ ifọpo meji to ti bẹrẹ iṣẹ, eyi yoo se iranwọ lati mu adikun ba iye owo dọla. Eyi tumọ si pe ọwọngogo yoo walẹ, ti ile aye yoo si rọrun fun araalu."
Bakan naa lo fikun pe adiku yoo de ba iye owo epo.
"Ileeṣẹ ifọpo yii yoo pese epo bẹtiro, disu, kerosini fun Naijiria, iye rẹ yoo walẹ, bẹẹni awọn nnkan mii yoo walẹ."
Ọjọgbọn Dandago fikun pe ti Naijiria ba lo ileeṣẹ ifọpo naa daada, ilọsiwaju yoo de ba eto ọrọ aje, ti ile aye yoo si rọrun funn araalu.
Ileeṣẹ ifọpo Warri, eyi to wa nipinlẹ Delta, ni apa guusu bẹrẹ iṣẹ lẹyin ọpọ ọdun to ti wa lai ṣiṣẹ.
Ọga agba fun NNPC, Mele Kyari ni bo ti lẹ jẹ pe awọn ileeṣẹ naa ti bẹre iṣẹ , o si ni awọn nnkan ti wọn si n se si.
O ni ileeṣẹ ifọpo Warri ni ipele mẹta , to si jẹ pe ipele akọkọ ni wọn wa bayii.
Aarẹ Bola Tinubu ṣapejuwe sisi ileeṣẹ ifọpo gẹgẹ ọkan lara awọn aṣoyọri rẹ ni ọdun 2024 to fi ireti sọkan ọmọ Naijiria.
Bakan naa ni Aarẹ rọ Kyari ati awọn ikọ rẹ pe ki wọn jaramọ iṣẹ lati tete pari lori ileeṣẹ ifọpo ti Kaduna.
Kyari ni "ileeṣẹ ifọpo Kaduna, iyanlẹnu ni yoo ba de."
Ninu ọdun 2023 ni wọn ṣe ifilọlẹ ẹbu ti wọn ti n fọ eporọbi (refinery), ti ileeṣẹ Dangote nipinlẹ Eko.
Ẹbu naa to jẹ ti gbajugbaja olokoowo, Aliko Dangote, ni wọn kọ si agbegbe Ibeju-Lekki, ni iroyin ní o tobi julọ nilẹ Africa.
Aarẹ ana, Muhammadu Buhari ati awọn olori orilẹ-ede mii ati èèkàn ilu ni o peju sibi ayẹyẹ naa.
Bakan ninu oṣu kọkanla ọdun 2024 ẹbu ifọpo orilẹede Naijiria to wa ni ilu Port Harcourt, ni ipinlẹ Rivers ti bẹrẹ si ni fọ epọrọbi pada.
Agbẹnusọ NNPCL, Femi Soneye lo kede igbesẹ yii, o si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi aṣeyọri nla.