A máa lo ọ̀nà míràn láti gba ìdájọ́ b'íjọba bá já wa kulẹ̀- Bàbá Yetunde tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nílé ààfáà n'Ilorin

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alfa Ibrahim Lawal, Baba to bi Hafsat, akẹkọọ obinrin ilẹ ẹkọ College of Education ti ipinlẹ Kwara ti wọn ba oku rẹ nile Aafaa kan nilu Ilọrin laipẹ yii ni oun gbagbọ pe awọn to ṣekupa ọmọ oun gbe igbesẹ na lati fi se etutu ọla ni.

Lawal ni bi o tilẹ jẹ pe awọn gbagbọ ninu ileeṣẹ ọlọpaa, awọn yoo ri pe awọn gba idajọ ododo pẹlu ọna miiran ti ijọba ati ileeṣẹ ọlọpaa ba ja wọn kulẹ.

O ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to ba oun ninu jẹ pupọ, to si ni oun setan lati lo ọna miiran lati ri idajọ ododo ti ijọba ba kuna lati ri pe idajọ ododo jẹyọ.

Baba Hafsat ni oun mọ pe ilu le, oun ko si fẹ sọ ohun ti mọlẹbi n gbero; ṣugbọn oun fẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa ri pe wọn fun awọn ni idajọ ododo.

"A fẹ idajọ ododo fun ọmọ wa Hafsat, ọmọ to ni ọja ọla ni."

O fi kun un pe "fun eeyan kan lati sekupa, a n gbe ọkan le ileeṣẹ ọlọpaa fun ohun to yẹ ṣugbọn ti eyi ko ba wa si mimu sẹ, a yoo lo ọna miiran lati wa idajọ ododo fun ọmọ wa."

Bẹẹ ba gbagbe, ọwọ ọlọpaa tẹ aafaa kan, ti orukọ rẹ n jẹ Mohammed Bello, lori ẹsun pe oun lo ṣeku pa ọrẹbinrin rẹ.

Amọsa, Aafaa Bello sọ pe aisan semi-semi lo pa oloogbe naa, kii ṣe oun.

Ṣaaju ni ọlọpaa ti kọkọ fi ṣikun ofin mu Bello, lẹyin ti wọn ṣawari ibi to kun Hafsat Lawal, to ni oun pade loju opo Facebook si lekiri-lekiri.

Ninu fidio ifọrọwerọ kan to gba ori ayelujara ni afurasi naa ti sọ pe oun kun ẹya ara oloogbe naa lọna ṣe ọrọ iku rẹ ni oku oru.

Bello ṣalaye pe ọrẹbinrin oun ni ni Hafsoh, nigba to dele oun lo sọ pe ebi n pa oun, ti oun si jade lọ lati ra ounjẹ fun.

Gẹgẹ bi afurasi naa ṣe sọ, o ni nigba ti oun yoo fi paa dele, oun ba to n mi gulegule, ti eemi rẹ ko si jake.

O ni "ọrẹbinrin mi ni Hasoh, ori Facebook ni a ti pade, emi kọ ni mo pa, akoba ni ọrọ yii jẹ fun mi.

"Nigba to dele mi, o sọ pe oun ko tii jẹun, mo si jade lọ lati lọ ra ounjẹ fun, nigba ti mo maa fi pada dele, niṣe lo n mi gulegule."