You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Òṣìṣẹ́ mọ́ṣúárì méjì kó sí gbaga ọlọ́pàá fẹ́sùn títa ẹ̀yà ara òkú ní Osun
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ti kéde pé àwọn ti nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́sàn-án fẹ́sùn wí pé wọ́n ń ta ẹ̀yà ara ènìyàn àti omi tí wọ́n fi ń wẹ òkú.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Osun, Emmanuel Giwa-Alade ṣàlàyé pé àwọn òṣìṣẹ́ ní iléeṣẹ́ tí wọ́n ń gbé òkú gbamọ́ sí méjì wà lára àwọn afurasí náà.
Ó ka Johnson Daniel, Adetunji Okunade, Olaniyan Azeez, Balogun Temitope, Oladapo Hammed, Kazeem Rasaq àti Asaka Rauf bíi àwọn afurasí tí wọ́n fòfin gbé lórí ọ̀rọ̀ náà.
Giwa-Alade ní àwọn gba ìròyìn kan pé Daniel, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé ìgbóòkúpamọ́ sí ní Ipetu-Ijesa, ń ta ẹ̀yà ara òkú fáwọn èèyàn.
Ó ní àwọn èèyàn tó ń ta ẹ̀yà ara òkú náà fún ló máa ń lò ó fún ṣíṣe oògùn lọ́kan-ò-jòkan.
Ó sọ pé Daniel ti jẹ́wọ́ pé òun àti òṣìṣẹ́ mìíràn, Adetunji Okunade ni àwọn jọ ń pawọ́pọ̀ láti jọ máa ta ẹ̀yà ara òkú àti omi tí wọ́n bá fi wẹ òkú fún àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà fi kun pé nígbà tí àwọn ṣe àyẹ̀wò ilé àwọn afurasí tí àwọn mú náà, àwọn bá nǹkan tó jọ orí èèyàn ní ilé Asaka Rauf àti Oladapo Hammed.
Bákan náà ló ní àwọn bá pátá obìnrin àti ìwé tí wọ́n kọ nǹkan ìṣègùn sí ní ilé Balogun Temitope Asimiyu.
Giwa-Alade tún sọ pé àwọn nawọ́ gán àwọn afurasí tó ń pè fún ìdásílẹ̀ Yoruba Nation ní ìpínlẹ̀ Osun.
Ó ní ọjà Obada ní ìlú Ikire ni ọwọ́ àwọn ti tẹ Oluwafemi Fagbuyi, níbi tó ti ń pàrọwà fún àwọn èèyàn láti gbàgbé nípa orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, pé kò sí nǹkan tó ń jẹ́ Nàìjíríà.
Ó ṣàlàyé pé Fagbuyi ń sọ fún àwọn ará inú ọjà náà pé Nàìjíríà ti dópin láti ọdún 2014, ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n da Nàìjíríà sílẹ̀, tó sì ń gbé àsíá Yoruba Nation sókè.
Ó fi kun pé àwọn ti ṣe gbogbo ìwádìí tó yẹ, tó sì ṣokùnfà táwọn fi nawọ́ gán àwọn afurasí méjì mìíràn, Joy Faseyiku àti Alabede Janet.
Ó sọ pé gbogbo àwọn afurasí náà ni àwọn ti gbé lọ sí ilé ẹjọ́ tí ìgbẹ́jọ́ sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí wọn ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Osun.