You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ni àdínkù ìdá mẹ́wàá tí NBS kéde pé ó bá ọ̀wọ́ngógó túmọ̀ sí?
Àjọ tó ń rí sí òǹkà ní Nàìjíríà ìyẹn National Bureau of Statistics, NBS ti kéde pé àdínkù ti bá ọ̀wọ́ngógó ní Nàìjíríà.
Àtẹ̀jáde ti NBS fi sójú òpó wọn lórí ìkànnì ayélujára X lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kejì, ọdún 2025 ní àdínkù ìdá mẹ́wàá (10.32%) ló bá ọ̀wọ́ngógó nínú oṣù Kìíní ọdún 2025.
Wọ́n ní ìdá mẹ́rìnlélógún (24.48%) ni ọ̀wọ́ngógó fi wáyé ní oṣù Kìíní ọdún 2025, tó sì jẹ́ àdínkù sí ìdá mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34.8%) tó wà ní oṣù Kejìlá, ọdún 2024.
NBS ní ọdún kan ni àwọn ń lò láti fi ṣe òdiwọ̀n bí nǹkan ṣe wọ́n sì báyìí, ní ìbámu pẹ̀lú nǹkan tí wọ́n ń ṣàmúlò ní àgbáyé dípò lílo ọdún 2009 tí àwọn fi máa ń ṣe ìgbéléwọ̀n rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Wọ́n ní èyí túmọ̀ sí pé ìdá mẹ́rìnlélógún ni owó ọjà, owó iṣẹ́ fi wọ́n sí, tí a bá ṣàgbéyẹ̀wò rẹ̀ pẹ̀lú iye tó jẹ́ ní oṣù Kìíní, ọdún 2024.
Bákan náà ni wọ́n sọ nínú àtẹ̀jáde náà pé iye owó oúnjẹ ni àdínkù bá di ìdá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26.08%) ní oṣù Kìíní ọdún 2025 láti ìdá mọ́kàndínlógójì (39.84%) tó jẹ́ nínú oṣù Kejìlá, ọdún 2024.
Ẹ ó rántí pé nínú oṣù Kẹwàá, ọdún 2024 ni olùṣirò àgbà Nàìjíríà, Adeyemi Adeniran kéde pé àwọn fẹ́ ṣe àtúntò bí àwọn ṣe máa ń ṣe ìgbéléwọ̀n ọ̀wọ́ngógó.
Adeniran ní ìgbésẹ̀ náà ń wáyé láti wà ní ìbámu pẹ̀lú àyípadà tó ń wáyé lẹ́ka ètò ọrọ̀ ajé.
Ó ní ìgbéléwọ̀n tuntun yìí yóò ṣàfihàn nǹkan táwọn èèyàn Nàìjíríà ń kojú lásìkò yìí àti irú ìgbé ayé táwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú.
Ẹ̀wẹ̀, àwọn onímọ̀ sọ pé kíkéde pé àdínkù ti bá ọ̀wọ́ngógó kò túmọ̀ sí pé àdínkù ti bá iye tí àwọn èèyàn ń ra nǹkan lọ́jà.
Àwọn onímọ̀ náà gbàgbọ́ pé ó túmọ̀ sí pé bí nǹkan ṣe ń wọ́n sí ni àdínkù bá kìí àdínkù owó ọjà gangan.
Wọ́n wòye pé ọ̀pọ̀ ilé àti àwọn ilé ìtajà ló ń kojú ọ̀wọ́ngógó ohun àmúṣagbára tí wọ́n ń lò nínú ilé àti okoòwò wọn, bí Nàìjíríà ṣe kéré sáwọn ilẹ̀ òkèrè lọ́jà àgbáyé, iye tí wọ́n ń kó ọjà wọ Nàìjíríà, owọ táwọn èèyàn fi ń wọkọ̀ àti àìsí ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.
Wọ́n ní ìjọba nílò láti ṣe àtúngbéyẹ̀wò àwọn ètò wọn lórí àwọn nǹkan yìí tí àdínkù yóò bá bá iye tí àwọn èèyàn ń ra ọjà pàápàá oúnjẹ.