Ìjọba Nàìjíríà gbọdọ fòpin sí Ìkọlù IPOB tó n ṣẹlẹ kíákíá-Abdulrahman Dambazau

Olori Ikọ ologun tẹlẹri fun orilẹede Naijiria, ọgagun Abdulrahman Dambazau ti ṣe apejuwe Ikọlu awọn alakatakiti IPOB gẹgẹ bi ohun ti oyẹ ki awọn ọmọ ologun orilẹede yii mu ni okunkundun ṣaaju eto idibo ọdun yii.

Ọrọ Dambazu ko ṣẹyin iṣẹlẹ ijinigbe ọmọbirin ologun ti awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB jigbe ninu oṣu kejila ọdun 2022,

ati awari ileeṣẹ ti o n se awọn ohun elo bombu ti o tobi julọ ni apa guusu ila oorun ti awọn ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Ebonyi ri laipẹ yii.

Dambazu ni lọdun 2022 ti o kọja yii nii awọn ipinlẹ to wa ni agbegbe ariwa iwọ oorun orilẹede Naijiria ni o kun fun orisirisi iwa ibajẹ bi igbenipa ati iwa ijinigbe ati awọn iwa ọdaran miran.

O ni orilẹede yii tun doju kọ iṣoro Latọwọ awọn ọmọ ogun IPOB ti wọn dun kooko ti won si n hale mo awon ara guusu ila-oorun orilẹede yii

ti wọn si tun won lati maje ki eto idibo ọdun 2023 yii ṣẹṣẹ tabi koyori si nkan ti awọn ara ilu n fẹ.

Kíni ọ̀nà àbáyọ sì ìgbé sumọmi

Minisita teleri fun ọrọ abẹnu safihan re pe, "ti a ba ni ka soro Lori eto abo oriledeyi, koye ka foju ara nikan woo.

Gege bi o se so oni ejoo lowo, ninu oro ti o nsele yii".

Dambazu ni ki ṣe lilọ agbara lo le yanju rẹ bikose isejọba rere.

Ijọba gbọdọ yanju Ọrọ ẹkọ,ipese iṣẹ ilẹra to peye,ayika to dun wo, ipese iṣe fun awọn alainiṣe jẹ awọn ọna ti ijọba gbọdọ mojuto ki iwa akatakiti le kase nle ni orilẹede yii.

O ni ijọba gbọdọ ṣetan lati mu adinku baa iṣẹ ati oṣi ki ilọsiwaju to loorin le jọba.