You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìnira tí mò ń rí nídìí iṣẹ́ báńkì ló mú mi di awakọ̀ èrò ìgboro
Obirin kan to n wa ọkọ ero igboro, Abigail Jeremiah, ti ṣalaye fun BBC eredi to ṣe fi iṣe banki silẹ di awako.
Abigial, to n fi ilu Abuja ṣebugbe sọ pe igbesẹ naa bẹrẹ lasiko ti ajakalẹ arun Covid-19 mi gbogbo agbaye titi laarin ọdun 2019 si 2020.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, iṣe banki to n ṣe tẹlẹ naa ko rọrun lasiko naa nitori pe o jẹ ọkan lara awọn to maa n wa onibara fun ile ifowopamọ to ti n ṣiṣẹ.
O ni “Wahala iṣẹ banki naa tip ọ ju fun mi gẹgẹ bii ẹni to maa n wa onibara, nitori naa ni mo ṣe fi iṣẹ ọhun silẹ, ti mo si di ẹni to n joko sile.
“Mo ba ọrẹ mi kan sọrọ loke okun, o bere pe ṣe mo le wa ọkọ daadaa, mo si dahun pe bẹẹni, bi mo ṣe bẹrẹ niyẹn.
Mo koju ọpọ ipenija nidi iṣẹ naa
Abigail ṣalaye fun BBC pe ọpọ ipenija loun dojukọ lati ọdọ awọn mọlẹbi oun, paapaa awọn obi ati ọkọ oun lori iṣe naa.
O sọ siwaju si pde ọkọ oun gbogun ti oun lọdun kinni ti oun bẹrẹ iṣẹ naa ko to pada juwọ silẹ.
“Lọpọ igba ti mo ba lọ gbe awọn eeyan ni papakọ ofurufu, wọn maa n sọ pe ah, ṣe obirin lo fẹ wa ọkọ yii ni? Rara o!
“Amọ ohun ti wọn ko mọ ni pe ọwọ awọn ọkunrin ni pupọ awọn ijamba oju popo to pọ ju ti maa n waye.”
O pari ọrọ rẹ pe oun mọ iṣẹ naa daadaa to bẹẹ ti oun le wa ọkọ fun ọpọ wakati ati fun ọna jinjin rere.