You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ìye tí o gbọ́dọ̀ ní tí o bá fẹ́ rìnrìnàjò tàbí lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní UK láti ọdún 2025
Orilẹede United Kingdom (UK), ti fi kun owo ti awọn arinrinajo to ba fẹẹ waa kawe tabi ṣiṣẹ niluu naa ni 2025 yoo maa san.
O ti tojọ mẹta ti orilẹ-ede naa ti n gbe igbesẹ ti ko ni i jẹ ki awọn arinrinajo to n wọle, ṣe akoba fun ile gbigbe ati ọrọ aje wọn.
Idi eyi ni wọn ṣe ni ajoji to fẹẹ waa kawe tabi ṣiṣẹ yoo ni lati fi awọn ẹri owo rẹ to ni han, ko too le ri UK wọ.
Gẹgẹ bo ṣe wa loju opo ayelujara UK, ajoji to ba fẹẹ waa kawe nibẹ, lẹyin ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2025, gbọdọ ni £1,483 fun itọju ara rẹ loṣu, niluu London.
Fun awọn ti ko gbe ni London, wọn gbọdọ ni £1,136 loṣu fun nina.
Bi o ba fẹẹ kẹkọọ fun iwe ẹri 'Masters niluu London, o gbọdọ ni £1,483 lapo iṣuna rẹ, oṣu mẹsan-an ni yoo fi wa bẹẹ, Apapọ eyi yoo jẹ £13,347.
Fun jijẹ-mimu ati igbayegbadun, owo ti ajeji gbọdọ ni bi wọn ṣe wi ni £1,136, fun oṣu mẹsan-an.
Eyi yoo jẹ £10,224, fun awọn ti ko gbe ni London.
Eeyan gbọdọ ni owo yii lapo ikowosi rẹ, o kere tan, fun ọjọ mejidinlọgbọn leralera ki o too le bẹrẹ igbesẹ fisa gbigba.
Ṣaaju ayipada yii, owo ti akẹkọọ gbọdọ ni loṣu ko ju £1,334, yoo si lowo naa bẹẹ fun oṣu mẹsan-an to ba fẹẹ kawe ọhun ni London.
Nigba ti wọn gbọdọ ni £1,023 tẹlẹ fun oṣu mẹsan-an, bi wọn ba wa nita London.
Ṣugbọn bi iwọ ba ti n gbe ni UK tẹlẹ, afikun owo yii ko kan ọ, bakan naa si ni awọn orilẹede kan naa yoo jẹ anfaani yii pẹlu.
Àfikún bá owó mọ̀lẹ́bí náà
Ijọba UK n ṣe awọn ayipada kan to mu afikun ba owo ti awọn mọlẹbi to ba n wọle siluu naa yoo ni lati san.
Tẹlẹ, £18,600 lowo naa, o ti di £29,000 bayii, yoo si tun wọn si i nibẹrẹ 2025, owo naa yoo di £38,700.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ijọba n ṣe awọn ayipada yii, ki awọn ololufẹ to ba n wọlu waa ba ẹnikeji wọn ma baa di iṣoro si wọn lọrun.
Wọn ni awọn fẹẹ kawọn eeyan ti ṣetan lati ṣe fisa fawọn to n de si ọdọ wọn.
Ijọba UK fẹ ki awọn to n mu ẹbi wọn wọle, ni ikapa lati gbọ bukaata wọn.
Tọkọ-taya to ba fẹẹ wọ UK pẹlu fisa mọlẹbi yoo nilo owo ọtọ fun ọmọ wọn.
Wọn yoo ni lati ni £3,800 lọdun kan, fun ọmọ kan, iyẹn fun ọmọ akọkọ.
£2,400 ni owo ti wọn gbọdọ ya sọtọ fun awọn ọmọ kọọkan yooku ti wọn ba tun fẹẹ mu wọ UK.
Ṣugbọn o, wọn ni eeyan yoo bọ ninu iru owo yii, bi ọmọ rẹ ba jẹ ọmọ oniluu lati EU, Iceland, Liechtenstein, Norway, Switzerland.
Ti wọn ko si ni kọnu-n-kọhọ kankan nilẹ tẹlẹ nipa jijẹ ọmọ oniluu nibẹ.
Fun awọn ti wọn ti n gbe UK tẹlẹ pẹlu fisa mọlẹbi, ti wọn ko si lowo yii lọwọ fun ọmọ kọọkan, wọn yoo ni lati fi ẹri han, pe ọmọ naa ti n gbe ni UK fun ọdun meje latigba ti wọn ti bi i.
Fún àwọn tó kàwé tó fẹ́ẹ́ wáá ṣiṣẹ́ fún ìgbà àkọ́kọ́ ní UK
£29,000 ni UK sọ pe wọn yoo san lati fi han pe awọn le da gbọ bukaat ara awọn, ki wọn si sanwo ile ti wọn yoo maa gbe ni UK.
Ẹni to fẹẹ waa ṣiṣẹ ni UK yii gbọdọ ni gbogbo amuyẹ ti oṣiṣẹ gbọdọ ni, eyi ti ọfiisi to n ri si eyi fọwọ si.
O gbọdọ ni iye owo ti wọn n fẹ ninu akanti rẹ fun ọjọ mejidinlọgbọn ki o too bẹrẹ eto fisa gbigba.
Ṣugbọn to ba jẹ pe ileeṣẹ rẹ lo fẹẹ ran ọ lọ si UK naa, awọn ni wọn yoo sanwo naa fun oṣu akọkọ.
Bakan naa ni ijọba UK tun ṣe awọn afikun pẹẹ-pẹẹ-pẹẹ kan si owo fisa awọn eeyan to kan fẹẹ rin irinajo afẹ lasan. (Tourist visa).
Wọn ṣe fun ti mọlẹbi, tọkọ-taya, ọmọde.
Wọn waa ṣe amojukoro ni ti awọn ti wọn ba ipenija ara kan, awọn ti wọn n wọle nipasẹ ẹbun ti wọn ni, awọn ológun, eleto ilera tabi awọn ti iṣẹ wọn jọ bẹẹ.