Ọwọ̀ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin kan pẹ̀lu N25 million tó fẹ́ẹ́ pín níbi ìdìbò

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ṣinkun bayii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, sọ pe ọwọ awọn ba ọkunrin kan, Shehu Patangi, to ko owo to to miliọnu mẹẹẹdọgbọn naira (N25 million) lọwọ lọjọ idibo.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe wi, o jọ pe afurasi naa fẹẹ fi owo ọhun ra ibo lọwọ awọn oludibo ni.

Ẹ o ranti pe atundi ibo ti a mọ si by-election n waye lawọn ipinlẹ kan lorilẹede yii bayii. Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, Mansur Hassan,fi sita, ṣalaye pe ile itura kan ni ọwọ ti ba Patangi, nigboro ipinlẹ Kaduna.

Atẹjade ọlọpaa fi ẹsun kan an, pe afurasi naa n gbiyanju lati ba awọn kan lẹdi apo pọ, ki wọn si maa pin owo naa fun awọn oludibo ni ẹkun-un Chikun/Kajuru ti ibo ti waye.

Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Kaduna ṣe wi, apapọ owo ti wọn ba lọwọ Shehu Patangi, jẹ ₦25, 963 million.

Alukoro fi kun un pe Patangi ti jẹwọ, bẹẹ lo si tun n beere fun aforiji.

Nípìńlẹ̀ Ogun, òṣìṣẹ́ INEC méjì wọ gàu pẹ̀lú owó tí wọ́n bá lọ́wọ́ wọn

Bakan naa, ni ipinlẹ Ogun, ọwọ ọlọpaa ti ba awọn eeyan meji kan ti wọn jẹ oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC.

Alukoro ọlọpaa Ogun, SP Omolola Odutola, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Abamẹta ti atundi ibo waye nipinlẹ naa, pe Ọgbẹni Toryem Joe-Stans ati Arabinrin Mandara Aminat, ti wọn jẹ oṣiṣẹ ajọ INEC pẹlu awọn mi-in ni awọn mu.

Odutola ṣalaye pe nnkan bii aago meji ku iṣẹju mẹẹẹdogun ni ikọ ọlọpaa to n wọde ni Iperu Remo, da ọkọ ayọkẹlẹ Mitsubishi ti nọmba rẹ jẹ LAGOS AKD 887 HT, duro.

Ọgbẹni Toryem Joe-Stans ati Arabinrin Mandara Aminat lo ni wọn wa ninu ọkọ naa pẹlu awakọ to n wa wọn.

Nigba ti wọn yẹ ọkọ naa wo ni wọn ba milionu meji aabọ owo naira nibẹ (₦2,500,000.00) bi Odutola ṣe wi.

Nibi ti wọn ti n fi ọrọ wa awọn eeyan naa lẹnu wo lo ni Joe-Stans Toryem ti jẹwọ, pe otẹẹli kan loun ti gba owo naa lọwọ ọkunrin kan to pe ni "Political Solution."

O ni aṣẹ ọga oun loun si tẹle.

Ṣaa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Ogunlowo, ti paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ lori awọn tọwọ ba naa.

O ni ki wọn fi wọn pamọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeren na bi iwadii ṣe n lọ.

Atundi ibo to waye nipinlẹ Ogun yii ni ti ẹkun-un Remo Federal constituency.

Ijọba ibilẹ mẹta lo ko sinu ti i ṣe Remo North, Ikenne ati Sagamu.

Oloogbe Abilekọ Adewunmi Onanuga, ti awọn eeyan mọ si Ijaya, lo n ṣoju ẹkun mẹtẹẹta nile aṣofin Abuja, ki iku to pa obinrin naa loṣu Kin-in-ni ọdun 2025 yii.

Eyi lo mu aaye rẹ ṣofo, ti atundi ibo si tori rẹ waye bayii.