Ọ̀rọ̀ Natasha Akpoti-Uduaghan kò tíì tán o, wo ohun tójú rẹ̀ tún rí nílé ẹjọ́ lónìí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbẹjọ ẹjọ ti aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria, Godswill Akpabio ati Gomina ana nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello pe Sẹnetọ, Natasha Akpoti-Uduaghan ti bẹrẹ lọjọ Aje.

Ile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja ni igbẹjọ naa ti n waye.

Sẹnetọ Natasha to n ṣoju aringbungbun ipinlẹ Kogi ni ile igbimọ aṣofin agba Naijiria n koju Yahaya Bello ati Akpabio lori ẹsun iwa ọdaran ori ayelujara.

Gẹgẹ ohun ti oju wa to ni ile ẹjọ, Aṣofin Natasha wa si ile ẹjọ pẹlu ọkọ rẹ.

Ọfiisi agbẹjọro agba lorilẹede NAijiria , OAGF ati ileeṣẹ to n risi ọrọ idajọ lo n pẹjọ naa lorukọ olupẹjọ fun ifisun ẹsun mẹfa ti wọn fi n kan an lori iwa ibajẹ.

Lati oṣu keji ni iwa ti bẹ silẹ laaarin amofin Natasha ati Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Akpabio.

Lori ẹsun ibaorujọ ẹni jẹ laaarin Natasha, Bello ati Akpabio, lara ẹsun ti wọn ka si Natasha ni pe ọ pa irọ mọ aarẹ ile ẹjọ ati Gomina ana eyi to da alaafia ilu laamu.

Ẹwẹ ni oṣu kẹfa ọdun 2025, Amofin Natasha sọ fun ile ẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun mẹta ti wọn ka si lẹsẹ.

Ẹsun mẹta ti ọfisi agba fun agbẹjọro orilẹede Naijiria ka si lẹsẹ ni pe o pa irọ mọ Aarẹ ile igbimọ aṣofin pe o n gbimọ pọ pẹlu Gomina ana nipinlẹ Kogi, Bello lati ṣekupa a.

Lasko igbẹjọ naa, ile ẹjọ gba baali fun Natasha pẹlu aadọta milọnu ati oniduro kan.

Bakan naa ni oṣu keju, Ile ẹjọ giga paṣẹ pe ki wọn da Sẹnetọ to n ṣoju aringbungbun ipinlẹ Kogi, Natasha Akpoti-Uduaghan, pada sẹnu iṣẹ rẹ lẹyin ti ile aṣofin naa ni ko lo rọọkun nile fun oṣu mẹfa gbako.

Nigba to n gbe idajọ naa kalẹ, Onidajọ Binta Nyako sọ pe oṣu mẹfa ti wọn ni ko lọ rọọkun nile ti pọju

Nyako ni gẹgẹ bii abala 14(2) ofin to sọ nipa anfaani awọn aṣofin ṣe sọ, ijiya ti wọn fun aṣofin naa ko tọ ọ.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Ninu oṣu Keji ọdun 2025 ni ede aiyede ṣẹlẹ ni ile aṣofin agba Naijiria, laarin Aarẹ ile naa, Sẹnetọ Godswill Akpabio ati Sẹnetọ Natasha Akpoti-Uduaghan.

Akpabio paṣẹ lasiko ti ijiroro n lọ pe, ki awọn oṣiṣẹ alaabo gbe e jade lẹyin ti obinrin naa kọ lati joko ni aaye tuntun ti wọn fun, to si sọ awọn ọrọ ibinu.

O fi ẹsun kan Akpabio pe o mọọmọ fẹ pa oun lẹnu mọ ni, to si fẹ gba anfaani ti oun ni lati da si ijiroro ile, lọwọ oun.

Lẹyin gbogbo awuyewuye to waye lọjọ naa, ile aṣofin fi ẹsun kan Natasha pe o tapa si awọn ilana ile naa, pẹlu bo ṣe kọ lati jokoo si aaye ti wọn fun un.

Ọrọ naa de iwaju igbimọ to n ba awọn aṣofin wi, ṣugbọn Natasha kuna lati farahan niwaju igbimọ naa.

Lẹyin rẹ ni wọn kede pe wọn ti da a duro fun oṣu mẹfa.

Ọrọ ọhun pada di ti ile ẹjọ, pẹlu bi igun mejeeji ṣe pe ẹjọ ọtọọtọ lori rẹ.