Díẹ̀ ló kù kí ìròyìn òfegè da ìgbéyàwó mi ogójì ọdún rú - Lai Mohammed

Minisita fun iroyin tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Alhaji Lai Mohammed ni diẹ loku ki igbeyawo oun ogoji ọdun daru nitori iroyin ofege kan to gba ori ayelujara kan.

O sọ itan yii nipinlẹ Eko lasiko to n sọrọ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi Ọjọgbọ Wole Soyinka nipa ẹka iroyin ati iroyin ofege.

Mohammed ni ipa ti iroyin ofege n ko ni orilẹede Naijiria ni o jẹ ohun ti oun ko le sọ tan nitori oun naa salabapade ida keji rẹ.

“E gba mi lati sọ itan yii pẹlu yin, bi iroyin ofege ṣe fẹ da igbeyawo mi ogoji ru

“Nigba kan ni ọdun 2018, mo wa si Eko lati Abuja fun iṣẹ kan.

“Gẹgẹ bii mo ṣe ma ṣe mo pẹ ki to lọ sun sugbọn nibi ago mẹta oorun, iyawo mi ji mi pe ki n dide.

“Mo kọkọ bẹru boya, awọn ara ibi ti de sugbọn mo ri pe iyawo ko ṣe ibi pe nnkan bayẹn waye.

“Iyawo mi sọ fun pe, n jẹ mo mọ pe ọrọ nla to lagbara wa lati sọ.”

“Baba, Iku le wọle de ni igbekigba, ẹ jọr, ẹ jẹ ki emi gẹgẹ bii iyawo yin ni anfani si awọn owo yin to wa ni ilefowopamọ Ali Financial to jẹ 1.3b dọla.”

Mohammed ni oun ni ṣe ọrọ ko le di igba ti ilẹ ba mọ sugbọn Iyawo rẹ yari. O tẹsiwaju pe ẹsun ti iyawo rẹ fi kan lo da bi pe wọn ju ado oloro si lọkan.

O salaye siwaju pe iyawo rẹ ni “Baba, Iku le wọle de ni igbekigba, ẹjọr, ẹ jẹ ki emi gẹgẹ bii iyawo yin ni anfani si awọn owo yin to wa ni ilefowopamọ Ali Financial to jẹ 1.3billion dọla.”

Minisita tẹlẹ ni oun ko le gbagbọ pe iyawo oun le gbabọ iroyin ofege to jade lasiko naa pe awọn osisẹ ijọba paapa oun ni aduru owo naa ni ipamọ ni banki ni oke okun lasiko iṣejọba Aarẹ tẹlẹ, Muhammadu Buhari.

“Wakati meji ni mo lo, ti mo n bọ lara mi lati salaye fun iyawo mi pe ko si nnkan to jọ mọ bẹ ati pe iroyin ofege ni.

“Mo ni wa ẹrọ iṣiro ni ọganjọ oorun lati fi salaye pe ko si bi mo ṣe fẹ ni 1.3 billion dọla ni ipamọ loke okun.

“Mo salaye pe ma nilo ọgọrun ọdun le mẹrin lati le ko iru owo bẹ jọ to ba jẹ pe mo n ko gbogbo pamọ.

“Iyawo mi ni gbogbo aye lo gba iroyin naa gbọ ati pe awọn ọrẹ ti n bere owo lọwọ rẹ ati pe gbogbo igbiyanju rẹ lati sọ fun wọn pe ọkọ mi ko ni owo loke okun lo jasi pabo.”