You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléẹjọ́ tó ń gbọ́ awuyewuye èsì ìbò gómìnà l’Eko yóò gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀bẹ̀, Rhodes-Vivour, olùdíje LP lónìí
Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Eko, yoo gbe idajọ kalẹ lọjọ Ẹti lori boya ki wọn wọgile ẹjọ kan ti oludije ẹgbẹ oṣelu Labour, LP Gbadebọ Rhodes-Vivour pe tako gomina Babajide Sanwo-Olu.
Gbadebọ̀ Vivour-Rhodes n fẹ gba iyọnda ile ẹjọ naa lati gbọ ẹbẹ meji ninu ẹbẹ mẹsan an to gbe ka iwaju ile ẹjọ ọhun.
Akọkọ ẹbẹ naa ni lati ṣe afikun awọn ẹlẹri ti wọn fẹ pe.
Ẹbẹ keji ti oludije ipo gomina lẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Eko naa n gbe ka iwaju ile ẹjọ naa ni dida ẹbẹ ẹjọ wọn pọ mọ ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọlajide Adediran.
Alaga ile ẹjọ naa, Onidajọ Arum Ashom kede ọjọ ati gbe idajọ kalẹ lori ọr naa lẹyin to ti gbọ awijare igun gbogbo ti ọr kan.