Ọlọ́pàá Ilorin bẹ̀rẹ̀ sí ní wá Ọkùnrin tó pe ara rẹ̀ ní Alfa tó ń dúnkokò mọ́ oníṣòwò kan

Kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, lọjọ Aje, ọjọ Kejidinlọgbọn, Oṣu Kẹẹjọ ọdun 2023 sọ wipe ileesẹ ọlọpaa yoo fi arakunrin kan, Ayọdeji Sala, to n dunkoko mọ oniṣowo kan Tajudeen Umar ati Iyawo rẹ ni ṣọọbu ti wọn ti n ta Tẹlifiṣan lagboole Aláràn-án, niluu Ilọrin jofin.

Ti ẹ ko ba gbagbe, lọjọ Kọkandinlogun, Oṣu Kẹjọ yii, ni Sala Ayodeji ẹni ti iroyin kan ni o maa n pe ara rẹ ni Alfa amọ ti a ko le fi aridaju rẹ han, atawọn Alfaa mii kan lọ ka Tajudeen ati iyawo rẹ mọ inu ṣọọbu wọn lagbegbe Ọmọda, niluu Ilọrin, ti wọn si ni dandan ni ki wọn kuro ni ṣọọbu naa tori pe wọn n ṣe ipade iṣẹṣe nibẹ.

Ninu fidio to gba ori ayelujara kan ni Sala Ayọdeji sọ pe ohun ti ohun ṣe ko ṣẹyin ajọ ọlọpaa ni ipinlẹ ọhun.

O tun paa laṣẹ fun ile Alaran to gbe ṣọọbu fun Ayọdeji pe oun fun wọn ni gbendeke ọjọ mẹjọ lati da owo Tajudeen pada ki wọ si lee jade nitoripe ti oun ba pada ba a lẹyin ọjọ mẹjọ, wahala yoo sẹlẹ.

Ki ni esi awọn onile to fun Tajudeen ni ṣọọbu?

Awọn ile Alaran naa gba si i lẹnu nipa dida owo rẹ pada ti wọn si le e kuro ni ṣọọbu wọn lai fi akoko ṣofo.

Lati igba ti isẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni a gbọ wipe Ayọdeji ti na papa bora ti ẹnikẹni to fi mọ mọlẹbi ati iyawo rẹ ko mọ ibi ti o sa lọ.

Kọmisọna naa sọ pe ajọ ọlọọpa ko lọwọ si ohun ti Alfa naa ṣe, wọn ko si fi igba kankan fun ẹnikẹni laṣẹ lati maa dunkoko mọ ẹlomiran nitori ẹsin tabi ohun miran.

O ni ibanilorukọjẹ lọrọ naa jẹ fun ileesẹ ọlọpaa awọn yoo si rii pe Ayọdeji Salau fimu kata ofin.

Kọmisọna naa sọ wipe ọwọ ofin yoo tẹ ọmọkunrin yii laipẹ tori pe ẹgbẹrun Saamu rẹ ko le sa mọ Ọlọrun lọwọ.

Lasiko to ni ki awọn mọlẹbi Ayọdeji, mọlẹbi Aláràn-án, ati Tajudeen wa rojọ lori bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, o ni dandan ni k'awọn mọlẹbi lọ wa Ayọdeji wa nibikibi ti wọn ba mọ nitori pe iwa ọdaran, lo hu labẹ ofin, ọwọ ofin si gbọdọ tẹ ẹ, yatọ si iwa buruku to hu o tun ba ọlọpaa lorukọ jẹ.

Ọlọpaa fun mọlẹbi Ayodeji ni gbendeke lati wa a jade

Kọmisọna Adelesi sọ fawọn mọlẹbi Ayọdeji, pe kilode ti wọn o le pe ọmọ wọn si akiyesi, "ṣe ẹ fẹ da Naijiria ru ni, ṣe tori pe Iyawo Tajudeen, jẹ ọmọ ipinlẹ Ọsun, ṣe iyẹn tumọ si pe o n ṣẹsin iṣẹse abi ko si musulumi nipinlẹ Ọsun?.

Bakan naa lo bẹnu atẹ lu iwa tawọn ara ile Aláràn-án, hu pẹlu bi wọn ṣe gbimọpọ lati le Tajudeen ati iyawo rẹ lojiji pe ki wọn kẹru jade ti wọn si ko owo ti wọn fi gba ṣọọbu naa le wọn lọwọ.

O ni dandan ni kawọn baba Ayọdeji, wa ọmọ wọn lawa ri ni gbogbo ibikibi to ba sa lọ ki wọn si wa fa a le ọlọpaa lọwọ o pẹ ju l'Ọjọru ọṣẹ yii, ti ọlọpaa naa yoo si maa wa a.

Awọn mọlẹbi wa fun kọmisanna lesi pe lati ọjọ Ẹti ọṣẹ yii, ni awọn ti n wa ọmọ awọn ti ko si wale ati pe nọmba ibaniṣọrọ rẹ naa ko lọ.

Ni ti Tajudeen, o ni oun fi ọrọ Ayọdeji le Ọlọrun lọwọ oun ko ni ẹjọ kankan lati ba a jẹ nitori pe awọn mọlẹbi Ayọdeji ti wa bẹbẹ ṣugbọn esi ti kọmisanna fun un ni pe ọlọpaa ti ṣetan lati ba Ayọdeji sẹjọ tori pe o tun ba ọlọpaa lorukọ jẹ.