You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èèyàn 32 jáde láyé nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi ní ìpínlẹ̀ Niger
Àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NEMA ti ní eeyan méjìlélọ́gbọ̀n (32) ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá okọ̀ ojú omi tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Niger lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Agbẹnusọ fún NEMA, Abdullahi Baba Ara sọ fún BBC News Hausa Radio ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀ pé èèyàn mẹ́jọ ni wọ́n ṣì ń wá nígbà tí wọ́n ti dóòlà àádọ́ta èèyàn láàyè.
Ṣáájú ni Ara ti sọ fún àwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́rú pé àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá náà lọ tó ọgọ́ta àmọ́ tó ní ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́.
Ó ní ohun tó ṣokùnfà ìjàm̀bá náà ni èrò àkójù tí wọ́n kó sínú ọkọ̀ náà, tí ọkọ̀ náà sì forí sọ igi nínú odò ló jẹ́ kó dànù
Ara sọ pé ìjọba ti gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ tí wọ́n ń pè ní "water marshals" tí wọ́n máa ma rí sí ìyè èrò tí wọ́n ń kó sí inú ọkọ̀ ojú omi àti pé àwọn èrò wọ aṣọ ìdáàbòbò tí wọ́n bá fẹ́ wọnú ọkọ̀ ojú omi.
Ó ní òun gbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà kò sí lẹ́nu iṣẹ́ nígbà tí ọkọ̀ ojú omi náà gbéra kúrò ní èbúté, tó sì ní ìwádìí ti ń lọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ìpínlẹ̀ Niger ni ìpínlẹ̀ tó tóbi jùlọ ní Nàìjíríà èyí tó máa ń mú àwọn èèyàn rin ìrìnàjò gba orí omi nítorí pé ó máa ń yá.
Ìjọba ti máa ń kàn án nípá fáwọn tó bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò gba orí omi láti máa wọ aṣọ ààbò nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni kìí tẹ̀lé òfin yìí.
Ní oṣù Kejì ọdún yìí, Mínísítà fún ètò Marine and Blue Economy, Adegboyega Oyetola gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti dènà ìjàmbá orí omi ní Nàìjíríà, tí iléeṣẹ́ náà sì kéde pé àwọn máa pín aṣọ ìdáàbòbò 42,000 káàkiri ìpínlẹ̀ méjìlá tí ìrìnnà ojú omi ti ń wáyé.
Ní oṣù Karùn-ún ọdún yìí ni NIWA bẹ̀rẹ̀ ìkéde pé kí láì sí aṣọ ààbò kò ní sí ìrìnàjò.
Èèyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi kan tó wáyé ní agbègbè Gausawa, ní ọ̀nà Malale sí Kainji ní ìjọba ìbílẹ̀ Borgu, ìpínlẹ̀ Niger.
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejì, oṣù Kẹsàn-án ni ìjàmbá ọkọ̀ náà wáyé.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìjàmbá náà ṣojú wọn ṣe sọ, nǹkan bíi aago méjìlá ọ̀sán ni ìjàmbá náà wáyé tí àjọ tó ń rí sí ìrìnnà ojú omi ìyẹn National Inland Waterways Authority (NIWA) sì dé síbi ìjàmbá náà ní nǹkan bí aago kan àbọ̀ ọ̀sán láti dóòlà àwọn èèyàn.
Ọkọ̀ ojú omi náà, tó jẹ́ onípákó, ni ìròyìn sọ pé ó kó àwọn èrò 138, tó sì dànù ní ọ̀gangan Shagunu-Dunga ní odò Kainji.
Àjọ NIWA sọ pé àwọn ọkùnrin mẹ́rìndínláàádọ́ta, obìnrin méjìdínlọ́gọ́ta àtàwọn ọmọdé ti wọn kò sọ iye wọn ni wọ́n móríbọ́ níbi ìjàmbá náà látàrí pé wọ́n wọ aṣọ ìdáàbòbò lórí omi.
Alákòóso àjọ NIWA fún ẹkùn Niger àti Kwara, Akapo Adeboye sọ pé iṣẹ́ ìdóòlà ṣì ń lọ lọ́wọ́, tí wọ́n sì ti yọ ọkọ̀ ojú omi tó rì ọ̀hún.
Ó ṣàlàyé pé àwọn àjọ NIWA Ti New Bussa, NIWA River Marshall, àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò àtàwọn olórí ìlú ni wọ́n jọ pawọ́pọ̀ ṣiṣẹ́ ìdóòlà náà.
Bákan náà ló fi kun pé iṣẹ́ ń lọ láti pọnkún ààbò àwọn èèyàn lórí omi láti ri dájú pé irúfẹ́ ìjàmbá báyìí kò wáyé mọ́.
Àwọn aráàlú, tó fi mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi náà jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe ìrànwọ́ f;un NIWA láti ri dájú pé wọ́n mú ààbò ẹ̀mí àwọn èèyàn ní òkúnkúndùn lẹ́nu iṣẹ́ wọn.
Iye ìgbà tí ọkọ̀ ojú omi ti gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn
Láàárín oṣù Karùn-ún sí oṣù Kẹjọ, ọdún 2025, ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi márùn-ún ló ti wáyé ní Nàìjíríà èyí tó ti mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lọ.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó wáyé yìí ló tún jẹ́ àlékún sí bí àwọn ọkọ̀ ojú omi ṣe ń fa ìjàmbá ní Nàìjíríà.
Ní oṣù Kẹjọ, èèyàn tó lé ní ogójì ló di àwátì nígbà tí ọkọ̀ ojú omi kan dànù ní ìpínlẹ̀ Sokoto.
Àtẹ̀jáde kan tí NEMA fi síta nígbà náà sọ pé ní ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹjọ ni ọkọ̀ ojú omi náà kó èèyàn tó lé ní àádọ́ta, tí wọ́n ń lọ sí ọ̀jà dànù.
NEMA ní èèyàn mẹ́wàá ni àwọn rí dóòlà nígbà tí àwọn tó lé ní ogójì di àwátì.
Bákan náà ni èèyàn mẹ́rìndínlógún tún pàdánù ẹ̀mí wọn nínú irú ìjàmbá bẹ́ẹ̀ ní oṣù Kẹjọ, ọdún 2024 nígbà tí ọkọ̀ wọn dànù sínú omi ní ìpínlẹ̀ Sokoto kan náà.
Ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, àwọn obìnrin mẹ́fà míì tún pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí ọkọ̀ wọn dànù ní ìpínlẹ̀ Jigawa.
Bẹ́ẹ̀ náà ni èèyàn mẹ́tàlá míì tún jáde láyé ní oṣù Keje kan náà nígbà tí ọkọ̀ wọn dànù ní ìpínlẹ̀ Niger.