You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ǹjẹ́ àwọn olórí ìṣèjọba tẹ́lẹ̀rí ní Nàìjíríà ní ipa tó jọjú nínú bí ìṣàkóso Nàìjíríà ṣe ń lọ báyì?
- Author, Umaymah Sani Abdulmumin
- Role, Journalist, BBC Hausa
Ọjọ ti pẹ ti ọrọ baba isalẹ ninu eto oṣelu ti n sokunfa awuye wuye ni orilẹ ede Naijiria, ni pataki julọ lasiko ti eto idibo ba gbode.
Ṣugbọn lẹyin gbogbo ọrọ baba isalẹ naa, ni ọkan o jọkan awọn Aarẹ tẹlẹri ti n ko ipa kan tabi omin ninu awọn eto to niise pẹlu oṣelu ati eto iṣejọba tiwa n tiwa ni Naijiria.
Lati bii ọdun marundinlọgbọn sẹyin ti eto ijọba awarawa ti fẹsẹ mulẹ ni Naijiria, ni a ti ri ọpọ awọn oloṣelu to n fojuhan lati gbe apoti ibo, bẹẹ ni wọn si n ba awọn adari tẹlẹri ninu oṣelu jiroro lori erongba wọn.
Lasiko iṣejọba Olusegun Obasanjọ, awọn eeyan kan gbagbo pe, Ọgagun Ibrahim Babangida to ti figbakan ri jẹ olori ologun ilẹ Naijiria, lọwọ ninu fifi Obasabjọ sipo naa.
Nigba naa, diẹ lara awọn oloṣelu asiko yi bii, Peter Obi oludije ẹgbẹ oṣelu Labour, wa lara awọn ti wọn da lẹbi wiwa atilẹyin Obasanjọ, iyẹn lasiko to igbapoti lọdun 2023.
Ẹwẹ, ohun to dun gbọ julọ lasiko yi ni, bi awọn to lẹnu daada ninu oṣelu ilẹ Naijiria ti bẹrẹ sini tẹle awọn adari tẹlẹri, bẹe ni oriṣiriṣi ariwisi n tẹnu awọn eeyan jade lori rẹ.
Ki lohun gan pato tawọn eeyan ilu n sọ?
Ko tii si eeyan kan pato to jade ni gbangba lati wa sọ nipa awọn oloṣelu naa ati awọn ibi ti wọn ṣabẹwo si.
Ṣugbọn fun apẹẹrẹ, laipẹ yi ni igbakeji Aarẹ tẹlẹri ni Naijiria Atiku Abubakar ti bẹrẹ igbesẹ ṣiṣe abẹwo si Muhammadu Buhari Aarẹ ana, nilu Daura, bakan naa ni gomina nigbakanri ni ipinlẹ Katsina Mallam Nasir El-Rufai naa gbe irufẹ igbesẹ ọhun, bẹẹ lẹnu ọjọ mẹta yi lo kansi Aarẹ tẹlẹri Olusegun Obasanjọ.
Peter Obi, ko si gbẹyin ninu ṣiṣe awọn eto to rọmọ iṣọkan awujọ, ati gbigbaradi fun agbekalẹ eto idibo ọdun 2027.
Awọn onimọ nipa ọrọ oṣelu tọka sii pe, ko tuntun mọ loju awọn eeyan nipa igbesẹ fifi ara mọ awọn adari, toripe, o jẹ ọna lati muki ibaṣepọ to lokimi wa laarin wọn, ati wi wo ọna min ti wọn fi lee gbori wọle.
Bawo ni ikopa awọn adari tẹlẹri naa ti mulẹ si?
Ọjọgbọn Kamilu Sani Fagge, Onimọ nipa ọrọ oṣelu ni fasiti Bayero to wa ni ipinlẹ Kano, Ṣatẹnumọ ọrọ wipe abẹwo ṣiṣe naa kii ṣe eyi ohun ti ko ṣẹlẹ ri lawujọ.
Pẹlu apẹẹrẹ pe, awọn gbajumọ oloṣelu to n gbapoti maa n saba tọ awọn agba ninu oṣelu lọ, ki wọn lee igi lẹyin ọgba wọn lati de ipo ti wọn ba n nanga si, bo tilẹ jẹ wi pe awọn naa ni atilẹyin laaye ara won.
“Wọn saba maa n ṣe eyi, nitori ki awọn adari ana ọhun maa ba tako igbapoti wọn lasiko idibo” Ọjọgbọn Fagge sọrọ.
Ọjọgbọ Fagge ni, iṣọkan ati ibaraṣepọ awọn oloṣelu naa lo maa n waye lasiko idibo, ṣugbọn ti yoo yato ti ibo ba ti pari, nipa bi wọn yoo ti bẹrẹ sini foju sọna fun eto idibo miran.
Peter Obi, ni Ọjọgbọn Fagge fi ṣe apẹẹrẹ ọrọ, lori bi Obasanjọ ti ṣe atilẹyin fun lọdun 2023, leyi to safihan ipa ti wọn ko lori awọn oludije ati eto idibo.
Ọjọgbọn Fagge ko sai tun tọka sii pe, ko pọn dandan ki abẹwo ṣiṣe si awọn Aarẹ tẹlẹri naa waye keeyan to lee jawe olubori nibi eto idibo,
O ṣalaye pe awọn ọna miran wa lati fa oju awọn oludibo mọra, tabi ki wọn maa ṣamusẹ ohun ti awọn adari wọn ba n ṣe lọwọ lọwọ,
Leyi to lee ṣeeṣe nipasẹ bi beere fun atilẹyin latọdọ awọn ajọ ilẹ okeere, nidi ati pese owo, ti awọn orilẹ yooku yoo si ṣatilẹyin fun iru ẹni bẹẹ.
Ọjọgbọn Fagge mẹnuba iṣesi awọn ọlọrọ kan laarin ilu to jẹ wi pe wọn kundun lati maa fi owo sugba oloṣelu kan lati gba apoti idibo, niwọn igba ti wọn ko ba ti dawọn duro .
Ko si ẹgbẹ kan to lọwọ ninu igbesẹ naa
Ọjọgbọn Kamilu ranti pe, ti ọjọ ori eeyan ba ti to ẹni to lee gbe apoti dibo, lo ti lanfaani ati ṣayipada awọn ero ọkan lori awọn ipinu kọọkan ninu oṣelu ṣiṣe.
Kamilu sọ pe, ohun to buru jai ninu ọrọ awọn oloṣelu ni wi pe, ifẹ inu ati ere ara wọn ni wọn saba maa n ja fun, toripe wọn ti ri oṣelu ṣise gẹgẹbi ọja tita ti ere gbọdọ jade nidi rẹ, tabi lati ko ọrọ jọ fun ara wọn.
Ọjọgbọn naa ko sai tọka sii pe, gbogbo oloṣelu lo ni ipa pataki lati ko lori awọn oludije, wi pe kii ṣe awọn Aarẹ ana nikan iyẹn ti asiko eto idibo ba ti de.