Ìdìbò bẹ̀rẹ̀ ní DR Congo nínú ìbẹ̀rù pé wàhálà le ṣẹlẹ̀

Eto idibo aarẹ ti bẹrẹ ni orilẹ-ede Democratic Republic of Congo, nibi ti miliọnu mẹrinlelogoji eeyan ti fi orukọ silẹ lati dibo.

Oludije mọkandinlogun lo n dije fun ipo aarẹ.

Aarẹ Felix Tshisekedi n dije fun saa keji.Bakan naa ni awọn agbegbe kan ko ti i ri awọn ohun elo idibo lọdọ wọn.

Botilẹ jẹ pe ko pẹ ti idibo bẹrẹ, iroyin sọ pe rogbodiyan ti n ṣẹlẹ ni awọn agbegbe kan.

Ni ilu Bunia, awọn eeyan kan to ti sa kuro nile nitori rogbodiyan to n waye tẹlẹ, ti ko si tun ni anfaani lati pada si awọn abule wọn lati dibo, kọlu ibudo idibo kan, ti wọn si ba awọn nnkan idibo jẹ ko to o di pe awọn ọlọpaa da wọn lẹkun.

Ṣaaju ni awọn eeyan kan ti fi ibẹru han lori aṣeyọri idibo naa, amọ ajọ eleto idibo, sọ pe ko ni si ewu.