You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bí Babaláwo ṣe fí àdá ṣá alábàgbé rẹ̀ lójú òórùn nìpínlẹ̀ Ogun ti ariwo sọ
Ọwọ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ọkunrin ti orukọ rẹ njẹ Idowu Talabi fun bi o ṣe ṣekupa alagbagbe rẹ, ẹni ọgbọn ọdun, Isau Oluwatobiloba ni agbegbe Ikene ni Ipinlẹ Ogun.
Afurasi ọhun ni ọwọ tẹ lẹyin ti iyawo oloogbe fi ẹjọ sun ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ẹkun Ikenne, pe nígba ti oun de sile ni ago mẹfa owurọ ni oun ba oku ọkọ oun ti wọn ti fi ada ṣaa ni iṣakuṣa.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Abimbola Oyeyemi, fi ransẹ si awọn akọroyin ni Iwadi ileeṣẹ ọlọpaa fihan pe niṣe ni Babalawo oun fi ada ṣa oloogbe naa nigba to n sun lọwọ lori ibusun rẹ.
Iwadi tun fihan pe ko si apa pe ẹnikeni ja wọ yara oloogbe, tí wọn ko si ji nkankan mu ninu ile ọhun.
Nigba ti wọn tẹsiwaju ni iwadi, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn pe gbogbo awọn alabagbe ninu ile naa lati wa rojọ, ti ọkan lara wọn ti orukọ rẹ ń jẹ Idowu Talabi si jẹwọ pe oun ni oun ṣekupa oloogbe naa.
Oyeyemi ni afurasí ọhun jẹwọ pe oun gbe igbesẹ naa nítorí oloogbe naa maa n pe oun ni ole, ti oun si mu ada lati fi gba ẹmi rẹ nigba to n sun lọwọ.
Kọmisona ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankole ti wa paalasẹ pe ki wọn gbe ẹjọ naa lọ sí ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwa ọdaran fun iwadi to pe ye.