‘Lẹ́yìn ọdún méjìlá tí ọkọ mi bá àwọn obìnrin sérékodé lọ, ìjà ti parí’

‘Lẹ́yìn ọdún méjìlá tí ọkọ mi bá àwọn obìnrin sérékodé lọ, ìjà ti parí’

Ọkọ iyawo kan to pada si ọdọ iyawo rẹ lẹyin to ba awọn obinrin mii lọ fun ọdun mejila gbako ti ba BBC Yoruba sọrọ lori iriri rẹ, bo ṣe kọ iyawo rẹ silẹ ati eredi to fi pada walẹ lẹyin to kọkọ ṣako lọ.

Odidi ọdun mejila gbako ni ọkunrin naa, Sunday Faboyede, fi iyawo rẹ silẹ pẹlu ọmọ marun un to si ba awọn obinrin mii lọ ko to pada wale.

Lẹyinorẹyin, ọkunrin ọhun pada wale, o bẹ iyawo rẹ, iyawo rẹ ọhun si gba a pada gẹgẹ bii ọkọ.

Tọkọtaya naa ṣalaye bi irinajo wọn ṣe bẹrẹ, oun to fa ituka wọn ati bi wọn ṣe tun pada di tọkọtaya lẹyin ọdun mejila gbako.

Bi ọgbẹni Faboyede ṣe sa kuro nile

Ninu alaye ti tọkọtaya naa ṣe, irufẹ iṣẹ ti ọkọ n ṣe atawọn ajoji obinrin ti ọkunrin ọhun, to jẹ ọlọpaa n ko lo fa ituka wọn.

Iya afin Foboyede sọ pe “Seme ti iṣẹ gbe wọn lọ ni ko jẹ ki wọn le maa wa sile lojojumọ, wọn maa n wale ni opin ọsẹ.

“Wọn ṣaa fẹ ọmọ Cotonou kan, wọn maa n pe iyẹn ni Tomato, iyẹn ni wọn fi kọkọ lọ fun ọpọ ọdun, emi ni mo lọ ja nibẹ o, mo lọ ja ni Seme lọjọ yẹn.

Ninu alaye ọkọ, o ni “Awa bii mẹrin la n ṣe iṣẹ nibẹ yẹn, onikaluku wọn lo ni ọrẹbinrin sibẹ, bi emi naa ṣe ni ọrẹbinrin niyẹn pẹlu wọn.”

Lẹyin ti ọgbẹni Faboyede fi Tomato silẹ, o tun fẹ obinrin mii, to jẹ alabagbe wọn tẹlẹ, to fi mọ ọpọ obinrin mii ko to pada sile.

“Bi mo ṣe pada wale”

Ọgbẹni Faboyede ṣalaye pe Eṣu lo faa ti oun fi n rin irinkurin pẹlo oriṣiriṣi obinrin.

O ni lẹyin ti iyawo oun wa ja nile ọrẹbinrin kan ti oun n gbe pẹlu rẹ ni onile naa fun oun ni iwe ‘kuro nile mi,’ loun bẹrẹ si n tu ero oun pa.

O fi kun pe akọbi ọmọ oun wa oun wa sinu ile naa lasiko kan amọ ti ọrẹbinrin naa sọ pe oun ko si nile, ti ko si gba ki oun jade sita.

Faborode ni “bi ọmọ mi ṣe pada yẹn, ounjẹ to gbe siwaju mi, mi o le jẹ, mo wa ni ṣe kii ṣe pe aye mi n bajẹ leleyii bayii?

“Ibi ti ọkan mi ti bẹrẹ si n ṣi diẹ diẹ niyẹn.”

Imọran fun lọkọlaya

Lẹyin ti ija ti pari laarin tọkọtaya naa, awọn ọmọ wọn ti darijin baba wọn, ọkan ninu awọn ọmọ naa si ti gbe awọn mejeji lọ soke okun lati gbafẹ.

Ninu imọran ọkọ, oni “amọran ti mo fẹ fun awọn ọkunrin ni ki wọn ṣọra wọn pupọ pupọ, ki wọn má jẹ ijẹkujẹ nita.”

Ninu imọran iyawo fun awọn obinrin to n la irufẹ iriri bẹẹ kọja, o ni “ki wọn ni suuru, ki wọn dẹ tun maa gbadura.”