‘Buga Won’ tí àwọn adájọ́ ‘Tribunal’ sọ, ìfọ̀rọ̀ṣeré lásán ni – Agbẹjọ́rò Oyetola

Lẹyin ti eeyan meji lara igbimọ ẹlẹni-mẹta ti ile ẹjọ to n gbẹjọ nipa magomago eto idibo, iyẹn Tribunal ti gba pe lootọ ni abusi idibo lọna aitọ waye to mu ki iye eyan to dibo gomina ni Osun pọ ju bo ti yẹ lọ, igun ti gomina to kuro lori alefa, Gboyega Oyetola tun ti sọrọ lati gbe lẹyin ohun ti awọn agbẹjọro Tribunal sọ.

Oloruntomiloba Olagunju to jẹ agbẹjọro fun Gboyega Oyetola mẹnuba ọrọ ijo “Buga Won” to tan kalẹ lọjọ ti idajọ naa jade pe Gomina tuntun Adeleke n jo kiri nigba ti ajọ INEC kede rẹ bii ajawe olubori.

Oloruntomiloba ṣàlàyé ni ọjọ Isegun pe ọrọ ayaba lasan kan ni orin "Buga Wọn to jẹ jade ninu atẹjade ile ẹjọ́ Tribunal.

Lẹyin ti wọn ṣàlàyé pe aridaju wa lóòótọ́ pe iye ibo ju iye oludibo lọ láwọn ibudo idibo kọ̀ọ̀kan to si fihan pe ati ẹgbẹ́ APC ati PDP ni igba ọrọ naa ṣi mọ lori ni ọrọ "Buga" jẹ jáde.

"Olujẹjọ keji ko ni le 'go lo lo lo' ati 'buga won' gẹgẹ bii ojulowo Gomina ti wọn dibo yan ni Ìpínlẹ̀ Oṣun lọjọ Kẹrindinlogun Oṣù Keje ọdun 2022," eyi ni ọrọ Tetsea Kume ẹni to ka ipinu gbogbo igbimọ naa jade.

Lati igba naa ni iriwisi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti gba ẹnu awọn ọmọ Naijiria kan ti awọn kan si n sọ̀rọ̀ pe idajọ naa lọwọ ninu bakanbakan.

Ẹwẹ, nigba to n fesi lori ọrọ naa nibi eto ori amohunmaworan Channels, Olagunju ni ọrọ naa ko si lara idajọ rara.

"Ninu òfin, mimẹnu ba Buga jẹ ohun ti a n pe ni "orbiter dictum" eyi to túmọ̀ si awọn ọrọ àyà bá, wọn kii ṣe ara ofin rárá."

O fi kun un pe bi ẹ ba wo gbogbo idajọ naa daadaa, ẹ o ri ibi ti o ti tọka si Onkọwe aláwọ̀ funfun nni Shakespeare.

Lati jẹ ki ọrọ wọn ye yekeyeke, awọn adajo maa n lo iru awọn ọrọ bayii.

Bakan naa lo ni iru awọn ọrọ bayii ko ṣeé pe ẹjọ́ Kotemilorun le lori.

Ẹwẹ, ile ẹjọ́ Tribunal wa ke si àjọ eleto idibo, INEC lati gba iwe ẹri mo yege ti wọn ti gbe fun Ademola Adeleke ati Igbakeji rẹ, Kola Adewusi ti wọn ti bura fun pada lọwọ wọn.

Ki ni igbesẹ ti Adeleke n gbe?

Àmọ́ṣá o, Adeleke ti leri lati pe ẹjọ́ Kotemilorun lori idajọ to daa duro gẹgẹ bii gomina Osun.

Gomina Adeleke ṣàpèjúwe idajọ naa bi eyi àbọ̀ idajọ to si fi kun un pe wọn ko ṣe e ni ibamu pẹlu ifẹ ọpọlọpọ oludibo.

O ni: "Mo n ke si awọn eeyan wa pe ki wọn fara balẹ. A maa pe ẹjọ́ Kotemilorun o si da wa loju pe idajọ ododo yoo waye.

"A fẹ fi da awọn eeyan wa loju pe a o ṣe ohun gbogbo to yẹ lati rii pe adé ẹtọ ti a gba yii mọ orí."