Àwòrán láti ibi ètò ìsìnkú Sénétọ̀ Ifeanyi Ubah

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Eto isinku ikẹyin fun Sẹnẹtọ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Ifeanyi Ubah waye lanaa Ọjọ Ẹti ni ilu rẹ, Nnewi.

Ubah lo ṣadede jaye laye ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje ọdun 2024, Aarẹ Bola Tinubu ṣapejuwe iku agba oloṣelu gẹgẹ bii ipadanu nla fun orilẹede Naijiria.

Ọpọ awọn eeyan jakanjakan ni ijọba ati ẹka okowo lo peju si ibi eto isinku naa lati bi ọla ikẹyin fun oloogbe.

Lara awọn eeyan to peju sibi eto isinku naa ni oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party fun ipo aarẹ lọdun to kọja, Peter Obi, Chris Ngige, Emyinnaya Abaribe, Osita Izunaso ati bẹẹ lọ

Aworan lati ibi eto isinku

Ta ni Ifeanyi Ubah?

Ifeanyi Uba jẹ gbajugbaja lẹka eto okoowo pẹlu ileeṣẹ Capital Oil Corporation.

Inu oṣu Kẹsan, ọdun 1971 ni wọn bi i, to si jẹ akọbi ninu awọn ọmọ meje ti baba rẹ, Alphonsus Ubah bi.

Ubah ti fẹ iyawo, o si ni ọmọ marun-un.

Agbegbe Otolo, ilu kekere kan nipinlẹ Anambra lo ti jade.

O lọ sile-ẹkọ Premier Academy Lugbe to wa ni Abuja, ṣugbọn ko pari rẹ nitori ailowo lọwọ awọn obi rẹ lati ran an nile ẹkọ.

O lọ si oriṣiriṣi idanilẹkọ nipa okoowo, ileeṣẹ ati ijọba.

Ọdun 2001 ni Ifeanyi da ileeṣẹ rẹ, 'Capital Oil' silẹ.

Bakan lo tun jẹ pe oun lo ni ẹgbẹ agbabọọlu Ifeanyi Ubah FC, ti wọn jẹ Gabros International Football Club, ti wọn si n kopa ninu idije ati ifẹsẹwọnsẹ ilẹ Naijiria, iyẹn Nigeria Premier League.

Ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni Ifeanyi Ubah ba jade lati du ipo gomina ipinlẹ Anambra lọdun 2014, ṣugbọn to padanu.

Lọdun 2019, Ubah jade du ipo aṣọfin agba lati ṣoju ẹkun Anambra South Senatorial District labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Young Democratic Party (YPP).

Ajọ eleto idibo, INEC kede rẹ lọdun 2019 gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori pẹlu ibo ọgbọn.