Gbèdéke tí Ecowas fún ológun tó gbàjọba ní Niger parí; wo ohun ti yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀

Gbedeke ọlọjọ meje ti ajọ Ecowas fun awọn ọmọ ogun to gbajọba ni orileede Niger lati da ijọba pada fun aarẹ Mohammed Bazoum ti pe lonii.

Ṣugbọn awọn alẹnulọrọ ṣi n wa ọna lati yanju aawọ to ba iditẹgbajọba yi de.

Lọjọ Aiku to kọja ni alaga ajọ Ecowas to tun jẹ aarẹ Naijiria, Bola Tinubu kede pe awọn ti fun awọn ọmọ ogun lọjọ meje lati da ijọba pada.

O ni bi bẹẹ kọ, awọn yoo ko ọmọ ogun jawọn.

Lati igba naa si ni oriṣiriṣi ikede ijiya ti waye debi pe wọn ja ina mọnamọna to lọ si orileede naa lati apa kan Naijiria.

Koda,wọn ti ibode pa ti eleyi si tumọ si pe ọja ko wọle bẹẹ si ni ko jade lati orileede naa.

Ni bayii ti gbogbo igbiyanju lati mu ki awọn ologun da ijọba pada fun Aarẹ Bazoum ko tii so eso rere, ki wa ni yoo ṣẹlẹ si gbedeke da ijọba pada yii?

Njẹ Ecowas yoo sun ọjọ gbedeke ?

Ọkan lara ọna ti Ecowas le gbe ọrọ yi gba ni ki wọn sun gbedeke.

Amọ eleyi le tun jẹ ki aawọ yi pẹ si ki wọn to ri yanju bo ti lẹ jẹ wi pe ohun tawọn igun mejeeji le sọ to mọgbọn wa ni pe ijiroro ṣi n tẹsiwaju tori naa sisun ọjọ ko buru pupọ.

Ohun to bu ọrọ yi ku bayi ni pe gbogbo igbiyanju ipẹtusaawọ yi lọna alaafia ti Ecowas n gba ko so eso rere.

Ikọ ti Naijiria gbe dide ni Ọjọbọ lọ si Niger ko ri nkankan mubọ gẹgẹ bi aṣeyọri.

Bi Ecowas ṣe n sọ igbesẹ tawọn fẹ gbe ni ijiya, bẹẹ naa ni ọmọ ogun Niger naa n leri leka.

Wọn kede pe awọn ko fẹ ni ajọṣepọ kankan pẹlu Nigeria,Togo,orileede Amẹrika ati France.

Bẹẹ ni wọn lawọn wọgile gbogbo adehun ajọṣepo ologun laarin awọn ati France to faaye gba ki wọn gbe ọmọ ogun orileede France to le ni ẹgbẹrun kan wọ Niger.

Nibi ti ọrọ de duro, Aarẹ Bazoum to wa latimọle ti n kerora iru ipo to wa ni ahamọ.

O fi ọrọ yi sita ninu apilẹkọ kan ti ileeṣẹ iwe iroyin Washington Post gbe jade.

Eleyi ti mu ki o kesi Amẹrika fun iranlọwọ lati da ijọba pada ki orileede Niger si bọ si oju ọna ijọba awarawa.

Lọjọ Ẹti, Amẹrika kede pe awọn yoo ran Niger lọwọ ati pe awọn yoo tẹsiwaju iranwọ aabo.

Ọna abayọ si dida ijọba pada

Ki ọrọ baa le niyanju, Ecowas ati awọn ọmọ ogun Niger gbọdọ joko fẹnu ko lori ọna ti wọn yoo fi da ijọba pada fun alagbada laipẹ.

O ṣeeṣe ki wọn fẹnu ko lori itusilẹ aarẹ Bazoum ati awọn alajọṣepọ rẹ kan tawọn ologun fi si ahamọ.

Eleyi le mu ki ọkan awọn to n tako iditẹgbajọba yi tutu nibi kibi ti wọn ba wa ni Africa tabi lagbaye.

Ecowas ti ṣaaju fẹnuko lori did ijọba pada ni orileede Mali ati Burkina Faso to jẹ alamuleti Niger tawọn naa wa labẹ ijọba ologun.

Gbogbo awọn ijiroro ti wọn n ṣe pẹlu wọn mu wahala lọwọ ko si daju pe wọn yoo da ijọba pada.

Sudan naa to jẹ pe ajumọṣe ijọba ologun ati alagbada ni wọn n lo lati ọdun 2019 to si yẹ ki eyi jẹ atọna fun idajọba pada falagbada ko ti ribi yanju ọrọ wọn.

Bi a ba si tun wo bi ija ṣe n waye laarin awọn ọgagun ilẹ naa ti wọn yapa lati le da ijọba ti wọn silẹ, ko daju pe alaafia yoo wa laipẹ.

Ṣe Ecowas ṣetan lootọ lati kogun ja Niger?

Ecowas ko sọ pato pe awọn yoo kogun ja Niger.

Awọn alaṣẹ Naijiria sọ pe bi awọn ko ba ri ọna gba mọ lawọn yoo ṣagbeyẹwo igbesẹ yi.

Aarẹ Tinubu sọ pe ''a le lo awọn ologun lati halẹ mọ awọn aditẹgbajọba ti wọn ba kọ lati tẹle aṣẹ wa''

Igba akọkọ kọ ni yi ti ajọ Ecowas ti lo ọmọ ogun lati da ijọba pada fawọn alagbada.

Ni 2017 nigba ti aarẹ The Gambia,Yahya Jameh, kọ la ti gbe ijọba kalẹ lẹyin ifidirẹmi ninu idibo, ologun ni wọn fi le kuro lori oye.

Amọ bi nkan ti ṣe ri bayii, yoo fẹ ṣoro diẹ lati lo ologun fi da ijọba pada ni Niger.

Akọkọ ni pe Niger jẹ ọkan lara awọn orileede to tobi ni Africa.

Lafiwe rẹ ati The Gambia iyatọ yoo wa nitori ko ni rọrun lati fi ọmọ ogun ranṣẹ sibẹ ni irọrun bi wọn ṣe ko ọmọ ogun lati Senegal wọ The Gambia nigba naa lọhun.

Ẹlẹẹkeji ni pe Naijiria to jẹ alagbara lagbegbe naa n koju awọn ipenija aabo labẹle.

Bo ba fi ọmọ ogun ranṣẹ si Niger, aye rẹ yoo yọ silẹ pẹlu ipenija to n koju pẹlu awọn agbesunmọmi bi Boko Haram ati Iswap.

Ẹlẹẹkẹta ni pe awọn orileede meji to mule ti Niger, Burkina Faso ati Mali sọ pe bi wọn ba fi le kogun ja Niger, awọn yoo ṣatilẹyin alabagbe awọn.

Nigeria ati Niger naa tun ni ibaṣepọ ọlọjọ pipẹ to munadoko.

Pupọ eeyan ni Niger n sọ ede Hausa ti eleyi yoo si ṣoro fawọn ọmọ ogun Naijiria to jẹ Hausa lati doju ija kọ ọmọ iya wọn ti ọrọ ba dogun.

Awọn orileede bi Algeria to mule ti Niger,orileede China ati Russia naa ti n sọ pe ki wọn tẹsiwaju ijiroro lati le fi yanju aawọ to wa nilẹ yi.

Lẹyin ijoko ijiororo ologun laarin ọjọ mẹta ni Abuja, olori awọn ologun Ecowas sọ pe awọn ti gbe ilana kalẹ lati le doju ija kọ awọn ologun Niger.

Wọn lo ku ki Naijiria foju agba wo ki igbesẹ kankan to le waye.

Nigeria, Ivory Coast, Senegal ati Benin lawọn ṣetan lati fi ọmọ ogun ranṣẹ ti Ecowas ba faṣẹ si.

Gẹgẹ bi iroyin ti Global Fire Power fi sita aijiria ni ọmọ ogun 135,000 ti Niger ko si ni ju ọmọ ogun 10000 lọ.

Bi a ba foju wo, a o ri pe ko le rọgbọ fun Niger ti ọrọ ba dogun.

Ohun to ku bayii ni ki ajọ Ecowas jẹwọ ararẹ nipa mimu alaafia wa lagbegbe to ṣe pe ko ribi dẹkun iditẹgbajọba ologun laarin ọdun mẹta to kọja sẹyin.