Lóòtọ́ ni òfin fi ààyè gba Gómìnà láti gba ìyọ̀ǹda ilé aṣòfin láti lọ tọ́jú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n...

Awọn amofin ti n ba BBC sọrọ lori ibeere ti araalu n beere nipa iye igba ti Gomina le kọwe si ile aṣofin lati gba iyọnda to ba fẹ lọ tọju ara rẹ.

Ibeere yi n waye latari ọrọ to gbode nipa Gomina ipinlẹ Ondo to fi iwe ranṣẹ si ile aṣofin ipinlẹ naa lẹyin oṣu kan kọja diẹ ti ko si lẹnu iṣẹ.

Agbẹjọro ati amofin kan ti o fi Ibadan ṣe ibujoko,Solihu Adebayo ṣe atupalẹ nkan ti ofin sọ nipa ọrọ yi.

O ni lootọ ni igbalaye wa fun Gomina lati kọwe fi to ile aṣofin leti pe oun fẹ lọ gba itọju amọ ofin yi ko sọ ni pato iye igba to le fi gba iru iyọnda.

Akeredolu ko tapa sofin

Lakotan alaye agbẹjọro taa ba sọrọ yi, o ni Gomina Akeredolu ko tapa si ofin kankan pẹlu bo ṣe fi iwe ranṣẹ si ile ti o si gbe ijọba kalẹ fun igbakeji rẹ.

''Lopin igba to ti ni iyọnda ile lati lọ isinmi itọju alaafia rẹ yi, ko si ohun to buru nibẹ.''

''Nkan ti ofin sọ ni gbigba aṣẹ lọwọ ile aṣofin lati fi gbọ bukata itju alaafia ara rẹ.''

Amofin Adebayo ni lopin igba ti ile naa si ti sọ pe igbakigba to ba gbọ bukata ailera rẹ lo to le pada si ẹnu iṣẹ,ko si ohun to tapa si ofin ninu nkan ti Akeredolu ṣe.

Ohun tí ìwé òfin Nàìjíríà sọ rèé nípa Gómìnà tí kò bá ní àlàáfíà láti ṣiṣẹ́ rẹ̀

Bi ẹ ba ti n fi ọkan ba ọrọ ilera Gomina ipinlẹ Ondo Rotimi Akleredolu bọ, o ṣeeṣe ki ẹ ti ri ọna mii ti ọrọ yi tun jasi.

Lọjọ Iṣẹgun yi ni awuyewuye tun bẹrẹ lẹyin ti igbakeji Gomina Akeredolu,

Lucky Adedatiwa to n dele de, fajuro si iroyin kan to gbode pe Akeredolu ko le gbe apa mọ.

Ninu atẹjade to fi sita niṣe lo bẹnu atẹ lu ''agbelẹrọ ahesọ ati ọrọ odi'' tawọn kan to fẹ da wahala silẹ kọ nipa ipo ilera Akeredolu.

O ni ko ko ko lara Akeredolu le ati pe ko ni pẹ pada sipo.

Bẹẹ naa ni Sẹnẹtọ Iyiola Omisore to jẹ akọwe agba ẹgbẹ oṣelu APC naa fi ọrọ sita wipe awọn akọroyin ṣi ọrọ gbe sita nipa ohun ti Alaga ẹgbẹ naa Sẹnẹtọ Abdullahi Adamu sọ nipa ilera Akeredolu ni.

O ni ko sootọ pe Akeredolu ko le gbe apa tabi ẹsẹ ati pe ko ni pẹ pada si ẹnu iṣẹ rẹ.

Atẹjade rẹ ree lẹkunrẹrẹ.

Kini ofin sọ nipa Gomina ti ko lalaafia lati ṣe iṣẹ rẹ?

Ibi a n lọ la pada de yi.

Labẹ ofin Naijiria ni paapa abala 189 ti wọn ṣe atunṣe rẹ sọ alaye nipa aile gbe apa tabi ẹsẹ ati ohun to tunmọ si fawọn to jẹ Gomina tabi igbakeji.

O ni itunmọ eleyi ni pe ''Gomina tabi igbakeji ko ni agbara lati ṣe iṣẹ ti wọn yan sipo nitori aini alaafia.''

Lati le fidi rẹ mulẹ pe Gomina ko le gbe apa tabi ko ni alaafia lati ṣe iṣẹ rẹ, ile aṣofin ni lati ṣe agbende igbimọ ti yoo ṣe ayẹwo ati iwadii to peye ti wọn yoo si jabọ fun olori ile.

Ti iwadii yi ba fi han pe ko lagbara lati ṣe iṣẹ rẹ, abala 189(2) labẹ ofin yi ni olori ile yoo buwọlu abajade yi ti wọn yoo si gbe jade ninu iwe ikede ijọba taa mọ si official Gazette.

Lati igba ti wọn ba ti ṣe eleyi, Gomina naa ko ni le dipo mu.

Awọn wo ni yoo wa ninu igbimọ iwadii yi?

Wọn o kan le yan eyikeyi dokita akọṣẹmọṣẹ sidi igbimọ yi lati ṣe iwadii ilera Gomina.

Iwe ofin Naijiria laa kalẹ pe Dokita marun un ni yoo wa ninu igbimọ yi.

Ọkan ninu wọn si gbọdọ jẹ Dokita to n tọju Gomina ọhun.

Awọn mẹrin to ku si gbọdọ jẹ ogbontarigi dokita to ni imọ nipa ẹka ti wọn yoo fi kopa ninu ayẹwo taa n wi yi.

Lati igba wo ni Akeredolu ti gba isinmi itọju ilera to gba?

Lọjọ Keje oṣu Kẹfa ni Gomina bẹrẹ isinmi ọlọgbọnọjọ lati lọ tọju ara rẹ.

O yẹ ko pada siṣẹ ni ọjọ Kẹfa oṣu Keje.

Ko kọkọ lasiko yi lati gbe agbara fun igbakeji rẹ ko maa ṣe akoso ijọba.

Amọ ṣa lẹyin ọpọ awuyewuye to fi mọ bi awọn ẹgbẹ alatako ṣe n sọ pe o yẹ ki Akeredolu gbe agbara fun igbakeji rẹ, Akeredolu pada kọwe si ile aṣofin lọjọ Kẹtala oṣu Kẹfa.

Ninu rẹ o ni ki wọn gbe akoso ipinlẹ naa fun igbakeji rẹ titi ti yoo fi pada sipo.

Lọjọ Kẹwa oṣu Keje to jẹ ọjọ mẹrin lẹyin igba to yẹ ki isinmi ilera Akeredolu pari ko si pada si ipo,o fi iwe ranṣẹ si ile aṣofin to si beere afikun iye ọjọ isinmi yi lọdọ olori ile.

Amọ ṣa ko sọ pato igba ti yoo pada si ẹnu iṣẹ.

Olori ile aṣofin Olamide Oladiji to gba iwe yi sọ pe o wa ni ibamu pẹlu amọran ti Dokita Akeredolu fun un wi pe ko sinmi lẹyin ti ara rẹ ba ya tan.

Oladiji fi kun pe eleyi wa ni ibamu pẹlu nkan ti iwe ofin Naijiria sọ ni abala 190 ti wọn ṣe atunṣe rẹ.

Abala ofin 190 yi sọ pe kete ti Gomina ba kọ iwe pe oun ko le ṣe iṣẹ oun, igbakeji Gomina ni yoo di ipo naa mu titi ti yoo fi kọwe pada lati fi wọgile iwe akọkọ to kọ.

Titi di asiko yi, Gomina ko ti kọ iwe mii lati sọ pe oun ṣetan lati pada sẹnu iṣẹ.