You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọwọ́ tẹ Bàbá tó ń fipá bá ọmọ rẹ̀, ọmọ ọdún 12 lopọ
Ọwọ ti tẹ ọkunrin agbalagba kan ti orukọ rẹ n jẹ, Arinze Obiwenite fun bo ṣe n fipa ba ọmọbinrin rẹ ọmọ ọdun mejila lopọ.
Wọn tun fi ẹsun kan an pe o n lo ọna aitọ fi tan awọn eeyan pe o ni ile ijọsin to ti n ṣe iwosan ni ile rẹ ni abule Abacha ijọba ibilẹ Idemili ni ipinlẹ Amambra.
Kọmisọna fun ọrọ obinrin nipinlẹ naa, Ify Obinabo fi idi rẹ mulẹ pe oun ni o lewajuu bi wọn ṣe kọlu ilegbe Baba naa lẹyin ti iroyin to wọn leti lori bi o ṣe ba ọmọ rẹ lopọ.
Bakan ni iwadii wọn fihan pe Baba ọhun ti awọn ọmọ rẹ mọle fun ọdun marun un, to si n ba eyi to dagba ju, to jẹ ọmọ ọdun mejila sun, to si tun ki ọwọ bọ oju ara awọn yooku to kere.
Kọmisọna Ify Obinabo, nigba to n fi idi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ BBC, o ni oun gan ni oun lewaju lati lọ ko awọn ọmọ naa kuro lọdọ Baba wọn.
O ni Iyawo mọkanla ni Baba naa ni sugbọn ọmọ naa ni o fẹran lati ma ba lopọ.
"Baba yii ti n tan awọn eeyan pe Kristẹni ni oun, pe o le wo awọn eeyan san lọwọ ailera to ba wọn fira laimọ pe isẹ buruku si wa lọwọ rẹ.
"A fi to Oba agbegbe naa leti, to si kesi Baba naa lati yọju si aafin sugbọn o kọjalẹ lati wa si aafi.
"Eyi lo bi awọn ọdọ ninu, ti wọn si gbera lọ si ile rẹ, nibẹ ni wọn ti sawari ibi to ti awọn naa mọ
"Baba mi maa n ba mi lopọ, tọwọ bọ awọn aburo mi loju ara"
Nigba ti wọn bi ọmọ rẹ obnirin to dagba ju pe ki lo sẹlẹ, O ni baba awọn ti n ti awọn mọle fun odidi ọdun marun un, to si n ba oun lopọ ni ọpọ igba.
Yatọ si iyẹn, ọmọdebinrin naa ni baba naa tun ma n ti ọwọ bọ oju ara awọn aburo oun pẹlu.
Kọmisọna ti wa ṣe ileri pe wọn yoo fiya jẹ baba naa labẹ ofin, nitori nnkan to lodi sofin ni ẹsẹ naa.
Bakan naa lo ni oun yoo pese agbegbe to dara fun awọn ọmọ lati se itọju wọn.