You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àjọ Yuroopu fẹ́ kọ afẹ́fẹ́ gáàsì Russia fi dípò ti Nàìjíríà
Ajọ iṣọkan Yuroopu , European Union ti fi lede pe awọn n wa afikun ipese afẹfẹ gaasi lati orilẹ-ede Naijiria.
Eyi ko ṣeyin igbeṣẹ ajọ naa lati dẹkun rira afẹfẹ gaasi lati orilẹede Russia.
Igbakeji aarẹ Ajọ European Commission Energy, Matthew Baldwin lo sọ bẹẹ lasiko ipade pẹlu awọn adari ni orilẹede Naijiria.
Awọn adari naa ni awọn n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe opin de ba eto aabo to dẹnukọlẹ ni Niajiria paapaa ni agbegbe Niger Delta, ti awọn si ṣetan lati ṣ Trans Niger Pipeline ni ẹyin oṣu to n bọ.
Kini eyi tunmọ si fun Niajiria ati Ajọ EU?
Ohun akọkọ ti eyi yoo pese fun Naijria ni pe wọn yoo maa gbe ohun elo afẹfẹ gaasi lọ si ilẹ Yuroopu.
Saaju asiko yii ni Ilẹ Yuroopu n gbe ida mẹrinla afẹfẹ gaasi wọle lati Naijiria pẹlu ileeṣẹ LNG Supplies.
Amọ biba ọpa epo jẹ ati iwa ọdaran ni agbegbe naa ti fa ki adinku ba iye afẹfẹ gaasi ti wọn n gbe lọ si oke okun.
Ajọ Yuroopu naa ni ileeṣẹ LNG ti sọ fun awọn pe iye afẹfẹ gaasi ti wọn n pese ni Naijiria yoo goke si pẹlu bi wọn ṣe fẹ maa gbe ti Naijiria lọ si oke okun.
Bakan naa ni wọn fikun un pe awọn alaṣẹ ni ẹka naa ni Naijiria ti ni ki awọn pada wa ni ipari Osu Kẹjọ fun ibeerẹ kikọ afẹfẹ gaasi naa lọ si oke okun.