Russia Ukraine Crisis: Amẹ́ríkà yóò pèsè ìrànwọ́ ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù dọ́là fún Ukraine

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tí kéde ìpèsè ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù dọ́là fún órílẹ̀ èdè Ukraine láti fi ràn án lọ́wọ́ lórí ètò ààbò.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Antony Blinken fi sórí ẹ̀rọ Twitter rẹ̀, owó náà wà fún pípèsè ààbò ní àwọn ẹnu ibodè, àti láti dá ààbò bo àwọn dúkìá ìjọba Ukraine.

Ìrànlọ́wọ́ Amẹ́ríkà yìí kò ṣẹ̀yìn bí ìkọlù Russia sí Ukraine ṣe ń tẹ̀síwájú.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní ọmọ ogun Russia tún ju àdó olóró sí ìlú Lviv, ibi tí wọn kò ṣe ìkọlù sí tẹ́lẹ̀ láti ìgbà tí ogun náà ti bẹ̀rẹ̀.

Ààrẹ Joe Biden lánàá ní orílẹ̀ èdè Poland ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn aláṣẹ Ukraine.