You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
US university in $250m payout: Fásìtì yóò sàn owó ìtanràn lórí aṣemáṣe dókítà wọn sì àwọn obìnrin tó n tọju
Ile ẹkọ fasiti California ti gba lati san owo itanaran to fẹẹ to $250m fawọn obinrin to le ni igba, ti wọn fẹsun fifi ibalopọ lọ ni, eyi ti wọn fi kan dokita ile ẹkọ naa.
Ọpọ obinrin lo fẹsun kan dokita James Heaps to wa ni ẹka ilera, UCLA, laarin ọdun 1983 si 2018, to fi siṣẹ nibẹ.
Koda, awọn obinrin to ni aisan jẹjẹrẹ pẹlu awọn to jade sita lati sọ pe o ṣe aṣemase wa lara awọn afẹsunkanni naa.
Ile ẹkọ fasiti naa ko bẹrẹ si ni ṣe iwadii dokita yii titi di ọdun 2017.
Aimọye ẹjọ ni wọn ti pe ile ẹkọ naa si lori iwa aṣemase dokita ọhun, ti wọn si ni wọn mọmọ daṣọ aṣiri bo dokita naa ni.
Lọdun 2019, adajọ paṣẹ pe ki wọn gba iwe aṣẹ rẹ gẹgẹ bi dokita lọwọ rẹ, lopin igba ti wọn yoo fi ṣe ẹjọ.
Fasiti naa sọ pe awọn lero pe owo itanran yi yoo jẹ ki awọn ti ọr naa kan ribi mu ọkan kuro nibi aburu to ṣe fun plu igbagbọ pe idajọ ti de.
Ẹsun aṣemasẹ mọkanlelogun ni wọn fi kan arakunrin Heaps pe o ṣe si awọn obinrin meje to si oun ko jẹbi
Ohun ti atẹjade fasiti sọ nipa isẹlẹ naa:
Àtẹ̀jáde kan láti UCLA ní ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Heap jẹ́ èyí tó ní ìjìyà lábẹ́ tó sì tàkò òfin ilé ẹ̀kọ́ náà.
Ó ní àwọn ènìyàn àti ìlú tí àwọn ń ṣiṣẹ́ fún ló jẹ àwọn lógún jùlọ pẹ̀lú ìrètí pé ìfẹnukò yìí yóò bú omi tútù sọ́kàn àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn.
Ṣùgbọ́n Kara Cagle, ẹni tó móríbọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn, tó fẹ̀sùn kàn Heaps lásìkò tó ń gbàtọ́jú ní ilé ẹ̀kọ́ náà sọ fún ìwé ìròyìn Los Angeles Times pé lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ, wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí òun.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun ìwúrí síbẹ̀ ó ba òun lọ́kàn jẹ́ pé àwọn kàn bá a lọ, gbogbo àwọn tó rí ìnira lẹ́yìn rẹ̀ nítorí UCLA kọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀.
Ìfẹnukò yìí kò dá ìgbẹ́jọ́ tí àwọn aláìsàn tó lé ní ọ̀dúnrún pè duro:
Ní oṣù keje ọdún tó kọjá, adájọ́ kan buwọ́lu kí Heaps san owó mílíọ̀nù mẹ́tàléláàdọ́rin Dọ́là lórí ẹjọ́ tí àwọn obìnrin tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún pè takòó.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn agbẹjọ́rò tó wà nídìí ẹjọ́ náà ti wí, Heaps ti fi ìgbà kan jẹ́ dókítà tí wọ́n ń sanwó fún jùlọ ní ilé ẹ̀kọ́ California .
Agbẹjọ́rò ọ̀kan lára àwọn obìnrin náà, John C Manley ní Heaps ló máa ń fi ọgbọ́n tẹ àwọn obìnrin lára tí yóò ní òun ń ṣe àyẹ̀wò fún wọn.
ẹ̀wẹ̀, àwọn obìnrin mẹ́ta mìíràn náà ti wọ́ ilé ẹ̀kọ́ Havard lọ sí ilé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn wí pé wọn kò kọbi ara sí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ ṣùgbọ́n ọ̀jọ̀gbọ́n John Comaroff jìyàn ẹ̀sùn náà.