Kwara Hijab Crisi: Èdè àwọn Krìsítẹ́nì àti Mùsùlùmí kò yé ara wọn lórí lílo Hijab

Awọn musulumi ati Kristiẹni ti wọn wa ni ti salaye ohun to tun fa akọtun ija ẹsin ni ile ẹkọ Oyun High School to wa nilu Ijagbo, nipinlẹ Kwara.

Nigba ti BBC Yoruba kan silu Ijagbo nipinlẹ Kwara nibi ti akọtun ija ẹsin tun ti suyọ laipẹ yii, awọn asaaju Kristiẹni ati Musulumi salaye idi ti wọn se gboju agan sira wọn.

Ninu ọrọ ti wọn ba wa sọ, irin kan ko tẹ fun ekeji, ti ko si si eyikeyi ninu wọn to gba pe igbesẹ ti ẹnikeji gbe tọna.

Koda, wọn n di ẹbi aawọ lilo Hijab naa ru ijọba pe ko se ojuse rẹ bo se yẹ, to si tun yẹ adehun to wa nidi gbigba awọn ile ẹkọ lọwọ awọn ẹlẹsin.

Ijọba fẹ yi orukọ ile ẹkọ wa pada ni, kii se ọrọ lilo Hijab lo n fa ija – Pasitọ

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, alaga fun ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi (CAN) ni ilu Ijagbo, Ẹni-ọwọ Olanrewaju Ajayi salaye pe ohun to n fa ija ju ọrọ lilo Hijab lọ ni awọn ile ẹkọ Kristiẹni.

O ni awọn ti gbọ pe ijọba fẹ yi awọn orukọ awọn ile ẹkọ to jẹ ti Kristiẹni pada ni amọ o kan kọkọ bẹrẹ pẹlu lilo Hijab ni.

“Ijọba n lo agbara oselu le wa lori nitori pe musulumi ni gomina wa, o si wa n lo agbara rẹ fawọn musulumi.

A mọ ibi ti wọn n lọ pe ibi ti wọn ti fẹ duro lori ọrọ naa kọja lilo Hijab, wọn kan n fi se bojuboju ni.

O ni adehun ti wa laarin awọn Kristiẹni ati ijọba nigba ti wọn fẹ gba ile ẹkọ lọwọ awọn ẹlẹsin pe akoso awọn ile ẹkọ yoo maa wa mi ikawọn awọn ẹlẹsin.

O fikun pe lati ẹyin wa, awọn Kristiẹni lo maa n sọ ẹni ti yoo di ọga ile ẹkọ ni awọn ile ẹkọ to jẹ ti awọn Kristiẹni naa.

Ti wọn ba fi gbe ọrọ Hijab wọle tan, diẹdiẹ ni wọn yoo yan ọga ile ẹkọ to jẹ Musulumi sawọn ile ẹkọ Kristiẹni lati maa se akoso ibẹ.

Ogun wa ni ile ẹkọ ti Kristiẹni yii jẹ, a ko si setan lati yọnda rẹ fun ẹnikẹni.”

Ajayi ni ọgbọn ẹwẹ ni ijọba n lo, awọn mọ ibi ti wọn n lọ, ki wọn si lọ jawọ ninu asẹ pe kawọn akẹkọ maa lo Hijab lawọn ile ẹkọ Kristiẹni .

BBC Yoruba tun tẹsiwaju lati ba awọn obi to jẹ musulumi to ni ọmọ ni ile ẹkọ Oyun High School sọrọ.

Ki ijọba lo gbogbo agbara rẹ paarọ orukọ awọn ile ẹkọ ẹlẹsin, ko si fi asẹ lilo Hijab lọlẹ - Obi akẹkọọ Musulumi

Mallam Ajibola Yusuf, lasiko to n ba BBC sọrọ ni oun ri ẹda iwe tijọba fi ọwọ si pe awọn akẹkọ to ba jẹ Musulumi le lo ibori, taa mọ si Hijab lọ sile ẹkọ wọn to ba wa labẹ akoso ijọba.

Ẹda iwe yii lo ni awọn obi ri tawọn akẹkọ musulumi fi n lo Hijab sugbọn ti awọn ọga ile ẹkọ to jẹ ti Kristiẹni n kọ fun wọn lati lo.

“Lootọ ni wọn ko mu awọn ọmọ wa nipa lati se ẹsin Kristiẹni ni ọna ti gbogbo aye yoo fi mọ, amọ wọn n mu wọn nipa labẹnu, ara rẹ si ni kikọ lati jẹ ki wọn lo Hijab.

Apẹrẹ jijẹ Musulumi ni lilo Hijab, ti ẹ ko ba si jẹ ki wọn lo, yatọ si igba ti wọn ba fẹ kirun, ẹ ti mu wọn nipa niyẹn.

A wa n rọ ijọba lati lo gbogbo agbara to ba wa ni ikawọ rẹ, ko fi paarọ orukọ awọn ile ẹkọ ẹlẹsin yii nitori abẹ akoso ijọba ni wọn wa.

Ohun to si le dẹkun aawọn ilẹ yii ni ki wọn fi asẹ lilo Hijab mulẹ ni awọn ile ẹkọ naa fawọn akẹkọọ to jẹ Musulumi.”

Yusuf ni awọn ko mọ ohun ti aawọ lilo Hijab yii le bi lọla, ti ijba ko ba gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ.

Ki lo fa aawọ ẹsin lawọn ile ẹkọ ni Kwara:

Ọdun 1974 la gbọ pe ijọba ipinlẹ Kwara gba akoso awọn ile ẹkọ girama ti awọn ẹlẹsin Kristiẹni ati Musulumi kọ lori awijare pe awọn ile ẹkọ ti ijọba kọ ko to.

Ijọba si ba awọn ẹlẹsin naa se adehun pe awọn yoo maa san owo awọn olukọ ti wọn ba n sisẹ lawọn ile ẹkọ ẹlẹsin naa, ti akoso ile ẹkọ yoo si wa lọwọ awọn ẹlẹsin.

Amọ ni bi ọdun kan sẹyin ni ariwo ta pe awọn ile ẹkọ kan nipinlẹ Kwara to jẹ ti Kristiẹni ko gba awọn akẹkọọ to jẹ Musulumi laaye lati lo Hijab, eyiun ibori wa sile ẹkọ.

Ọrọ naa fa rogbodiyan nla, ti ọpọ eeyan si se lese, ti aimọye dukia si bajẹ bakan naa.

Idi ree ti ijọba ipinlẹ naa se se ofin pe awọn akẹkọọ to jẹ Musulumi ni asẹ lati maa lo Hijab lawọn ile ẹkọ ijọba to n jẹ tawọn ẹlẹsin Kristiẹni.

Wahala naa ti lọ silẹ di ni ipinlẹ Kwara lati igba ti ijọba ti se ofin naa amọ se ni laasigbo naa tun dede su yọ ni ile ẹkọ Oyun High School to wa nilu Ijagbo.

Ipa wo ni aawọ lilo Hijab ti ni lori awọn ile ẹkọ ni Kwara:

O ti le ni ọdun kan bayii ti aawọ ẹsin ti n da omi alaafia ru ni awọn ile ẹkọ to jẹ ti Kristiẹni nipinlẹ Kwara.

Koda, aawọn naa ti mu ọgbẹ nla ba awọn eeyan kan lasiko rogbodiyan to waye ni ọdun to kọja.

Bakan naa ni ọpọ ile ẹkọ ni ijọba gbe ti pa nitori rogbodiyan naa, to si se ipalara fun eto ẹkọ lasiko naa.