Hijab crisis: Àwọn òbí gbé iléèwé ISI lọ síléẹjọ́ nítorí ọ̀rọ̀ Hijab wíwọ̀

Awọn obi nileewe girama University of Ibadan International School, ISI ti wọ awọn alaṣẹ ileewe naa ati ti fasiti Ibadan lọ siwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ pẹlu ẹsun pe wọn fi ẹtọ awọn akẹkọbinrin kan lori wiwọ ibori hijab dun wọn.

Ni ọjọ aje ni wọn pe ẹjọ naa ninu eyi ti wọn tunpe olukọ agba ileewe naa, Iyaafin Phebean Olowe ati alaga igbimọ alakoso ileewe girama ọhun, Ọjọgbọn Yinka Aderintọ lẹjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọrọ ede aiyede lori wiwọ ibori Hijab ti n ja ranyinranyin ni ọgba ileewe girama naa eleyii ti awọn alaṣẹ ileewe naa ni ko si aaye fun un labẹ ofin rẹ.

Amọṣa awọn obi naa ti wọn ni eyi tako ẹtọ awọn akẹkọbinrin ọmọ wọn gba ile ẹjọ lọ lorukọ awọn ọmọ wọn.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, alaga ẹgbẹ awọn obi nillewe girama University of Ibadan Internation School, ISI, Alhaji Abdulrahaman Balogun ni ẹbẹ mẹta ni awọn gbe ka iwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ lori ọrọ naa.

Gẹgẹ bi o ti wi, ẹbẹ akọkọ ni pe ki ileẹjọ naa fi idi ẹtọ ọmọniyan awọn akẹkọbinrin ọhun lati wọn ibori Hijab mulẹ, ẹbẹ keji ni ki ile ẹjọ o paṣẹ pe bi wọn ṣe se awọn akẹkọ to wọ hijab wọ yara iyaweka nileewe naa mọle fun ọpọlọpọ wakati ko bofin mu.

Bakannaa ni wọn tun nfẹ ki ile ẹjọ naa o gba awọn akẹkọ naa laye lati ṣamulo ẹtọ wọn si ẹsin to ba wu wọn.

Akitiyan lati gbọ tẹnu awọn alakoso ileewe naa lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ ko ti bọ sii.