You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Jawahir Roble: Hijab tí mò n lò kọ́kọ́ jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn agbábọ́ọ̀lù mi
Lọdun 2004 ni ẹbi JJ Roble fi ilu abinibi wọn, Somali silẹ nitori ogun, ti wọn si ṣe ibugbe tuntun mi i si Wembley ni ilẹ Gẹẹsi.
Ni bayii, oun ni obinrin alawọdudu akọkọ, to jẹ musulumi to tun n wọ hijab, to jẹ adari ere bọọlu nilẹ Gẹẹsi.
Afojusun rẹ ni lati jẹ iwuri fun ọpọlọpọ obinrin si i, lati maa gba bọọlu. Ati lati gbe awọn agbabọọlu obinrin ni England de ipo pataki ninu iṣẹ wọn.
O gba awọn ọdọbinrin ni imọran pe ko si ohun ti wọn ko le ṣe ti wọn ba ti gbagbọ ninu ara wọn pẹlu atilẹyin Olorun.