Mùsùlùmí ni mí ṣùgbọ́n ìrírí àkọ́kọ́ mi rèé nípa ọdún Kérésìmesì ní Canada, Muhammad Hussain ṣàlàyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iriri akọkọ arakunrin ẹlẹsin musulumi kan nigba ọdun keresi to fi soju opo Twitter ti di ohun tawọn eeyan n pin kaakiri.

Mohammad Hussain, to n gbe ni ilẹ Canada pinu lati ṣe ọdun Keresi pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ meji kan nitori isede to de wọn mọle.

Ohun toju rẹ ri nigba Keresi akọkọ rẹ yi, paapa nipa gbigbin igi keresi ati didana ounjẹ Keresi fjẹ iyalẹnu fun un.

Nitori naa lo fi ni ohun bẹrẹ si ni kọ nipa iriri yi soju opo Twitter-ibẹ lawọn eeyan ti bo bi igba ti eera bo ṣuga ti wọn si n pin kaakiri.

Ni bayi ẹni ọdun marundinlọgbọn naa sọ pe oun n foju sọna de owurọ ọjọ Keresi akọkọ ti oun yoo ba wọn ṣe.

O sọ fun BBC pe''Niṣe o n ṣe mi igba pe Harry Porter ni mi''

Ọgbẹni Hussain to ba wọn ṣe gbogbo pọpọsinṣin ọdun keresi- bi ka ba wọn ṣe apejẹ Keresi ni ọfisi tabi lilọ si ile ọrẹ rẹ laisun Keresi- ko lanfaani ati ṣe iru rẹ ri nitori idile musulumilo ti wa.

Ajakalẹ Corona virus to de ju onikaluku mọle lo mu ki oun ati awọn alajijọgbe rẹ gbimọran lori ọna ti wọn yoo fi ṣe ọdun Keresi.

Nigba ti eeyan kan s pe ki wọn da ina ounjẹ orisi mejila ni arakunrin Husdsain ni ko sa'buru nibẹ.

"Mo kan fẹ ran wọn lọwọ nipa ipalẹmọ ọdun Keresi ni''

Bi mo ti ṣe n wo wọn, mo ri pe wọn mọ iṣẹ yi ṣe ju mi lọ.Apẹrẹ iṣẹlẹ yi kan ni igba ti wọn n fi ohun ẹṣọ sara akaba ile, mi o ribi ṣe daada ṣugbọn ẹnikeji mi yara ṣe tiẹ''

Gbogbo awọn nkan to ri nipa ipalẹmọ Keresi yi lo fi soju opo rẹ ni Twitter, kia lawọn eeyan ti ṣalabapin rẹ niye igba to le ni 100,000

Lẹyin ti awọn eeyan bẹrẹ si ni pin ọrọ to kọ yi ni ọrẹ rẹ kan mu imọran wa pe ki o fi oju opo awọn ajọ ẹlẹyinju aanu sibẹ ki awọn eeyan baa le da owo fun wọn.

O gba imọran yi ti wọn si ko owo jọ fun awọn ẹlẹyinju aanu meji to n pese ounjẹ, Milton Halal Foodbank ati Parkdale Food Centre.

''Iyalẹnu lo jẹ si mi'' ati pe ''eeyan pupọ lo ti n ta awọn alaini lọrẹ, awọn eeyan n sọrọ daada nipa igbiyanju wa''

Mohammad sọ pe oun n foju sọna di igba ti oun yoo ba awọn akẹgbẹ rẹ sọju Musulumi to si ni o ṣeese ki oun wa baba keresi ti yoo fun wọn lẹbun ni igba naa.

Lara ohun ti wn la kalẹ lati ṣe ni ọjọ Keresi ni pe wọn yoo dana orisisi ounjẹ mejila ti wọn yoo si jijọ ṣere kaadi tita nitori iṣede to wa nita

Kini kan ti Mohammad ni o n jẹ iyalẹnu fun oun ni bi awọn eeyan ṣe n duro lati tu ẹbun wọn ti wn ko kalẹ

''Diduro de asiko ti a o tu ẹbun wa n ṣemi bakan.Sẹbi awọn ẹbun naa lo wa niwaju wa yi?''

Awọn alabagbe rẹ sọ pe awọn yoo ṣi awọn ẹbun kan laisun ọjọ Keresi tawọn yoo si ṣi eyi toku lowurọ ọjọ Keresi.