You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ayé mà le o! Obìnrin ará Morocco pa olólùfẹ́ rẹ̀, ó fi se ìrẹsì
Obinrin ara Morocco kan ni United Arab Emirates ni wọn ti fi ẹsun kan pe o pa ololufẹ rẹ ti o si se oku rẹ fun awọn oṣiṣẹ ọmọ Pakistan jẹ.
Oṣu mẹta sẹyin ni wọn funra si pe o pa ololufẹ rẹ naa, ṣugbọn aipẹ yii ni aṣiri rẹ tu nigba ti wọn ba ọkan lara ẹyin ọkunrin naa ninu ẹrọ ilọta igbalode.
Obinrin naa to jẹ ẹni bii ọgbọn ọdun jẹwọ fun ọlọpaa pe, aarẹ ọpọlọ ṣe oun nigba ti oun pa ọkunrin naa ni. Wọn ni yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ.
Iroyin sọ pe ọdun meje ni ifẹ fi wa laarin oun ati ọkunrin naa. Iwe iroyin ilu naa sọ pe arakunrin naa fẹ lọ fẹ ẹlomiran ni o ṣe paa.
Awọn ọlọpaa ko sọ bi o ṣe pa ọkunrin naa, ṣugbọn wọn ni o fi oku ọkunrin naa se irẹsi ti o si fi fun awọn oṣiṣẹ kan ti o wa ni agbegbe naa jẹ.
Aburo oloogbe naa to wa sile lati beere rẹ ni o ri eyin rẹ ninu ẹrọ ilọta igbalode ti o si lọ agọ ọlọpaa lati fi ẹjọ sun pe ẹgbọn oun ti di awati.
Iwadii ti wọn ṣe lori eyin naa fi han pe ẹnu oloogbe naa lo ti jade.