You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Blac Chyna fẹ́ wá ta ìpara bórabóra Whitenicious ni Eko
Àjọ NAFDAC ni àwọn n fojú si ìpara bórabóra ti Blac Chyna ọmọ ilẹ̀ America n kó bọ̀.
Ajọ yii lo n mojuto ọrọ ounjẹ àti oogun lilo ni Naijiria.
Monica Eimunjeze to jẹ oludari ẹka to n ri si àṣìlọ nkan ni NAFDAC ṣalaye fun BBC pé ileeṣẹ naa ko ni ọrọ lati sọ lasiko yii ṣugbọn NAFDAC wa lati daabo bo àwọn eniyan Naijiria ni.
Blac Chyna n ko ipara bórabóra bọ si Naijiria
Arábirin olókiki ọmọ Amẹrika kan, Angela White, ti gbogbo eniyan mọ si Blac Chyna n bọ nilu Eko ni ọjọ isinmi, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu yii, ṣugbọn oun to n gbee bọ ni orilẹ-ede Naijiria ni o ya ọpọlọpọ eniyan lẹnu.
Owo to tó aadọrun ẹgbẹrun naira ni ikan iru ipara yii yoo jẹ ni owo Naira.
O fẹ wa ta ipara borabora rẹ ti o pe ni Whitenicious ni.
Lori ikanni rẹ lori Instagram, lo ti ṣalaye pe oun n ṣe agbajọwọ pẹlu awọn ti n ṣe ipara Whitenicious ni.
Blac Chyna to j'ẹ ẹni ọgbọn ọdun naa n pe awọn alatilẹyin rẹ ni orilẹ-ede Naijiria lati wa si ibi ayẹyẹ ti wọn yoo ti ṣi aṣọ loju ipara naa nilu Eko.
O kọ sori Instagram pe, "Ẹyin ara Eko, ẹ wa pade mi nibi ti a o ti ṣi aṣọ loju ipara mi Whitenicious ni ọjọ Aiku ni ile itaja. Gbogbo eniyan ni a pe."
Inu agolo kekere kan ti awọn onibara yoo ra ni iye owo bii ẹgbẹrun lọna aadọrun naira.
Ṣugbọn eebu ni awọn ọmọ Naijiria fi n ki kaabọ o.