#Pittsburg shooting: agbófinró gbé afurasí lọ sílé ẹjọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Pittsburg ni ipinlẹ Pennsylvania niṣẹlẹ yii ti wáyé ni orilẹ-ede Amẹrika.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eniyan lo farapa nigba ti afurasi naa da ìbọn bolẹ nile ijọsin Sinagọọgu ti wọn n pe ni Tree of Life lọjọ Abamẹta to kọja.

Awọn agbofinro ni lasiko ti ijọsin Sabbath wọn n lọ lọwọ lo kọju ibọn sawọn olujọsin naa.

Ẹsun mọkandinlọgbọn ni wọn fi kan ọkunrin ọmọ ọdun mẹrindinlaadọta yii bii didena ijọsin ati igbagbọ ẹlomii àti ipaniyan.

Oun funra rẹ naa faragbọgbẹ lasiko iṣẹlẹ nla ibi yii.

Awọn olujọsin ṣalaye pe isin akọkọ n lọ lọwọ ni nkan bii aago mẹwaa aaro ni ọkunrin yii wọle to si n yinbọn.

Ọpọlọpọ gba pé eyi jẹ ọkan lara ikọlu sawọn Juu to buru ju lasiko yii.

Bakan naa ni aarẹ Donald Trump to n tukọ Amẹrika ni gbogbo ohun to ṣẹlẹ ni gbogbo eniyan ri pẹlu ibinujẹ pe iwa yii buru jai lori ikanni rẹ pe:

Awọn agbofinro ṣi n ṣiṣe lọ lori iṣẹlẹ naa ni Pittsburg.