You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bali: Imam kọ̀ láti dá ìrun dúró nínú ilẹ̀ ríri Bali
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Àwọn ọmọ orílè-èdè Indonesia ti n kán sára sí Imam kan tó kọ láti dá irun dúró nígbà tí ilẹ rírí ṣẹlẹ ní ìlú Bali.
Imam náà ẹní ti orúkọ rẹ n jẹ Arafat dúró gidigba tí kò sì dá irun dúró tóun tí bí àwọn janmọọ to n kirun lẹyìn rẹ kan ṣẹ f'ẹsẹ fẹẹ.
Agbẹnusọ kan fún mosalasi As-Syuhada sọ fún ilé iṣẹ BBC pé àwọn tó n kirun lẹyìn imamu náà lawọn ''sadede gbọ tí àjà bẹrẹ sí ní mí to sì dàbí wí pé ilé náà yóò yà lulẹ̀ làbá sá asalà fún ẹmi wa''
Agbẹnusọ náà so wí pé Imam náà tẹẹ pá nítorí "Ọlọhun nìkan ló lè gb'ẹmi rẹ".
Ọkẹ àìmọye èèyàn lo ti ba ìṣẹlẹ ilé rírí náà tó waye ni erékùṣù Lombok lọ.