Ife ẹ̀yẹ àgbáyé: Ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ kan náà tó ti kópa níbẹ̀ rèé

Ife ẹ́yẹ àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìdíje ife ẹ́yẹ àgbáyé yóò wáyé lóṣù kẹfà lórílẹ̀èdè Russia

Bí ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ṣe ń ṣe kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọlé báyìí, ìwáàdí fihàn wí pé, lára àwọn ohun mèremère nípa ìdíje náà, láti ìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀ ní ìfarahàn àwọn ọmọ ìyá kan náà nínú ìdíje náà.

Lára àwọn ti a ri ṣajọ niyi:

Ottmar ati Fritz Walter( Orilẹede Germany):

Ottmar ati Fritz Walter( Orilẹede Germany)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ottmar ati Fritz Walter( Orilẹede Germany)

Nibi idije to waye ni ọdun 1954 lorilẹede Switzerland ni awọn ọmọ iya mejeeji yii ti kopa, ti wọn si fakọyọ.

Goolu mẹrin ni Ottmar gba wọle ninu idije naa ti Fritz si gba mẹta wọle.

Ipa ti awọn mejeeji yii ko ninu idje ọ̀hún fun ikọ agbabọọlu orilẹede West Gernmany nigbana ko kere, ló jẹ ki wọn gba ife ẹyẹ ọhun ni ọdun naa.

Bobby ati John Charlton (Ilẹ Gẹẹsi)

Bobby ati John Charlton (Ilẹ Gẹẹsi)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bobby ati John Charlton (Ilẹ Gẹẹsi)

Bobby ati John Charlton jumọ gba bọọlu fun orilẹede Gẹẹsi nibi idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 1966, eleyi ti ilẹ Gẹẹsi gba alejo rẹ.

John ni ẹgbọn ninu awọn mejeeji, apa ẹyin ni oun gba (defender) nigbati Bobby ni tirẹ n gba apa iwaju (Forward).

Ipa diẹ kọ́ ni awọn mejeeji yii ko lati rii pe ilẹ Gẹẹsi bori West Germany lati gba ife ẹyẹ agbaye lọdun 1966.

Ni ọdun 1966 yii kan naa ni Bobby gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ lagbaye, Ballon d'Or.

Wilhelmus (Willy) Antonius ati Reinier (Rene) Lambertus van de Kerkhof (Netherlands)

Wilhelmus (Willy) Antonius ati Reinier (Rene) Lambertus van de Kerkhof (Netherlands)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wilhelmus (Willy) Antonius ati Reinier (Rene) Lambertus van de Kerkhof (Netherlands)

Ibeji ni Willy ati Rene van de Kerkhof, ti awọn mejeeji si kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ni ọdun 1974 ati 1978 nibi ti wọn ti de ipele aṣekagba idije naa.

Frank ati Ronald de Boer (Netherlands)

Frank ati Ronald de Boer (Netherlands)

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Frank ati Ronald de Boer (Netherlands)

Ni idje ife ẹyẹ agbaye to waye lọdun 1994, ni awọn mejeeji yii ti jijọ kopa.

Bi a ko ba ni gbagbe, ni ọdun 1994 ni igba akọ́kọ́, ti orilẹede Naijiria, Super Eagles kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye lorilẹede Amẹrika.

Awọn ọmọ iya mejeeji yii tun kopa ni ibi idije naa to waye lọdun 1998 lorilẹede France.

Jerome (Germany) ati Kevin-Prince Boateng (Ghana)

Jerome (Germany) ati Kevin-Prince Boateng (Ghana)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Jerome (Germany) ati Kevin-Prince Boateng (Ghana)

Ohun to ṣe kayefi lori ọrọ Jerome ati Kevin-Prince ni pe, orilẹede ọtọọtọ ni wọn ṣoju fun ni idije naa.

Ni idije ife ẹyẹ agbaye to waye lorilẹede South Africa lọdun 2010, Jerome gba bọọlu fun Germany, Kevin-Prince ṣoju fun orilẹede Ghana, to jẹ orilẹede abinibi wọn gan an.

Awọn mejeeji koju ara wọn nibi idije naa lọdun naa, ṣugbọn Jerome lo rẹrin lọ sile pẹlu bi Germany ṣe na Ghana pẹlu ami ayo kan si odo.

Nigba ti wọn pada koju ni idije yii, to waye lorilẹede Brazil, ọmi oni goolu meji-meji ni wọn gba.