You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bose Omolayo Paralympian: Bí mo ṣe rí ọkọ fẹ́, tí mo tún bímọ lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ pé mi ò ni lè bímọ nìyí
Ami ẹyẹ ti Bose Omolayo ti gba gẹgẹ bi elere idaraya to n gbe irin kii ṣe kekere koda o ti rinrinajo lọ si ọpọ orilẹede kaakiri agbaye bayii.
Nigba kekere rẹ gẹgẹ bo ṣe sọ iriri to ni ni awọn kan ti sọ fun iya rẹ pe ko lọ ju u nu tori pe "ọmọ to n fi aya fa ko lee di nkankan laye".
Arabinrin Bose Omolayo sọ fun BBC Yoruba bi o ṣe padanu ẹsẹ rẹ ni kekere ni nkan bii ọdun mejila amọ ko jẹ ki eyi dii lọwọ lati sọ ala rẹ di mimu ṣẹ gẹgẹ bi elere idaraya.
Ni bayii, inu rẹ dun pe o ti n gbe igbe aye to wu u bayii ti inu rẹ si dun si iṣẹ to yan laayo.
Bakan naa ni o dupẹ pe o pada ri ọkọ fẹ to tun jẹ Ojiṣẹ Ọlọrun. Bakan naa lo bi ọmọ.
"Inu mi kan maa n dun ti mo ba ri awọn ọmọ ti mo bi toripe wọn ti kọkọ ni mi o ni le bimọ".
Bose mu iranti wa ni igba to bẹrẹ gbigbe irin gẹgẹ bi iṣẹ lẹyin to ti foju ri oniruuru ipenija laye rẹ bo ṣe n dagba.
O ranti awọn to gba iya rẹ nimọran lati lọ ju oun sori akitan tori wọn ni oun ko le da nkankan laye amọ iya rẹ kọ eti ikun si wọn to si tii lẹyin titi to fi di eeyan.
Bakan naa lo ranti ẹni to fi gbigbe irin lọ ọ ti ko si lee gbagbe laye laye tori oun naa ti di ẹni to n rinrin ajo lọ soke okun lẹnu iṣẹ yii ti o si ti gba ami ẹyẹ pupọ.