You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Jigan Baba Oja: Àṣírí tí ẹ kò mọ̀ rèé nípa ohun tó sọ mí di ẹlẹ́sẹ̀ kan
Gbajumọ oṣerekunrin, Abimbola Kazeem, Jigan Baba Oja ti kede pe kii ṣe abinibi ni ẹsẹ to n dun.
Oserekunrin naa to gbajumọ ninu ere tiata Yoruba, paapaa fun aṣa 'So mọ age mi ni' lasiko diẹ sẹyin, sọ eyi ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu tẹlifisan ori ayelujara Ojopagogo TV.
Jigan sọ pe wọn ko bi oun ni ẹni ti ko le fi ẹsẹ kan rin, o ni nigba ti oun wa ni ọmọ ọdun meje, aisan kan ṣe oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èmi àti Sanyeri ti tọrọ oúnjẹ jẹ rí nílé oninawo torí ebi, ká tó di gbajumọ oṣere
- Èmi tí wọ́n kọ́kọ́ pé ọkọ Bimbo kú gàn an ti di jálajála lórí ìròyìn burúkú náà- Jaye Kuti, ọ̀rẹ́ Bimbo Oshin
- Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrin Laide Bakare àti Kemi Afolabi nítorí ọkunrìn?
- "Ará Cotonou, Sunday Igboho kò gbọdọ̀ kú sọ́dọ̀ wa o, ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí"
- Awò ojú tí mò ń lò kìí ṣe akọ tàbí ìgbéraga, ohun tó fà á rèé - Helen Paul
- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ilé Kéú tó lú akẹ́kọ̀ọ́ bíi bàrà
- Ẹ dẹ́kun fífún ọkùnrin tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ní ìbálòpọ̀
- Akúṣẹ́ apẹja bọ́ sínú agbami ọrọ̀ lẹ́yìn tó rí èébì ẹja Wéèlì létíkun
Aisan naa sọ ọ di ero ileewosan, to si jẹ pe abẹrẹ ti wọn fun lati tọju aisan naa lo pada sọ ọ di ẹni ti ko le fi ẹsẹ kan rin mọ.
O ṣalaye pe gẹgẹ bi oṣere, ọpọlọpọ ere ni oun ni agbara ati ọgbọn lati ṣe, ṣugbọn wọn ki fun oun ni iru iṣẹ bẹẹ nitori pe wọn n 'ṣaanu ẹsẹ oun".
Eyi to n jẹ idiwọ fun bo ṣe yẹ ko ga to nidi iṣẹ tiata.
O ni agbegbe Shomolu nipinlẹ Eko ni wọn bi oun si, to si lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama nipinlẹ Eko bakan naa.
O lọ si fasiti Olabisi Onabanjo, Ago-Iwoye nipinlẹ Ogun fun eto ẹkọ giga, to si kẹkọ gboye nibẹ pẹlu.
Nipa nkan to gbe e de idi iṣẹ tiata, Jigan Baba Oja sọ pe lati kekere ni oun ti fẹran lati ma a kọrin Fuji, ti oun si ni awọn ọmọ ẹgbẹ.
O ni koda, wọn ma n pe oun si ibi ayẹyẹ fun orin kikọ, eyi si lo ni o jẹ ki oun mọ pe iṣẹ amuludun ni oun yoo ṣe.
Jigan sọ pe oun tun bẹrẹ orin takasufe 'hip pop', ko to o tun pada si idi orin Fuji.
O fikun ọrọ rẹ pe oun ma n kọkọ kọrin ni agbo ti Wasiu Alabi Pasuma ba ti fẹ ẹ kọrin.
O ni agbo Paso l'oun ti pade awọn oṣere loriṣiriṣi, eyi to mu ko pinnu lati darapọ mọ wọn pe boya okiki oun naa yoo yọ.