Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjíríà?

Nigba ti mo de buka lati jẹun lẹyin ti mo ja ero ni mo ri ẹru naa ti mo si da a pada- Mathew

BBC Yoruba maa n fọnrere iwa Omoluwabi to ṣe pataki pupọ ninu aṣa ati iṣe Yoruba.

Eyi lo jẹ ki a wa Baba Awakọ to ri ẹru ero to si da gbogbo ẹru naa pada.

Bawo ni ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ?

Ni budo ọkọ reluwe Babatunde Fasola ni ipinle Eko ni Mathew Okotie ti gbe awọn ero naa lọ sile itura ni GRA

Lẹyin ti awako Mathew ja awọn ero silẹ tan to fẹ jẹun ni buka lo rii pe wọn gbagbeẹru to si da a pada fun wọn nile itura ti wọn de si.

BBC ba Ogbeni Dimeji Adedeji to ni ẹru naa sọrọ o ni o ya oun lẹnu olootọ awako bayii ṣi wa ni Naijiria.

Egberun meta ni Demiji fun mi nigba ti mo da ẹru rẹ pada fun un- Mathew Okotie

Lati igba ti Mathew ti ṣe ootọ ni mo ti n lo o bi awakọ nigba kigba ti mo ba ti wa si Eko- Dimeji

Akọroyin to ni ẹru ti Mathew da pada rọ awọn ọmọ Naijiria lati maa ṣooto lẹnu iṣẹ wọn nigba gbogbo.

Bakan naa ni BBC ba Ogbeni Owolabi Azeez to jẹ igbakeji alaga gareeji ti wọn ti wọkọ ero naa yombo irufẹ iwa ootọ ti Mathew ni.

ArabinrinChristiana Odewade to jẹ ọmọ awakọ naa sọ fun BBC pe ootọ inu ni baba oun fi kọ gbogbo ọmọ rẹ.